9 A mọ̀ pé Kristi tí a ti jí dìde kúrò ninu òkú, kò tún ní kú mọ́; ikú kò sì lè jọ̀gá lórí rẹ̀ mọ́.
10 Kíkú tí ó kú jẹ́ pé ó ti kú ikú tí ó níláti kú lẹ́ẹ̀kan; yíyè tí ó yè, ó yè fún ògo Ọlọrun.
11 Bákan náà ni kí ẹ ka ara yín bí ẹni tí ó ti kú ní ayé ẹ̀ṣẹ̀, tí ó tún wà láàyè pẹlu Ọlọrun ninu Kristi.
12 Nítorí èyí, ẹ má ṣe jẹ́ kí ẹ̀ṣẹ̀ tún rí ààyè jọba ninu ara yín tí ẹ óo fi máa fààyè fún ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ara.
13 Ẹ má sì gbé ara yín sílẹ̀ bí ohun èèlò fún ẹ̀ṣẹ̀. Dípò èyí, ẹ lo ara yín fún iṣẹ́ òdodo, kí ẹ sì fi í fún Ọlọrun, ẹni tí ó lè sọ òkú dààyè.
14 Ẹ má jẹ́ kí ẹ̀ṣẹ̀ di ọ̀gá yín, nítorí ẹ kò sí lábẹ́ Òfin; abẹ́ oore-ọ̀fẹ́ ni ẹ wà.
15 Kí ló wá kù kí á ṣe? Ṣé kí á máa dá ẹ̀ṣẹ̀ nítorí pé a kò sí lábẹ́ òfin, abẹ́ oore-ọ̀fẹ́ ni a wà. Ká má rí i.