21 Àbí amọ̀kòkò kò ní ẹ̀tọ́ láti ṣe amọ̀ rẹ̀ bí ó ti wù ú bí? Bí ó bá fẹ́, ó lè fi amọ̀ rẹ̀ mọ ìkòkò tí ó wà fún èèlò ọ̀ṣọ́. Bí ó bá sì tún fẹ́, ó lè mú lára amọ̀ kan náà kí ó fi mọ ìkòkò mìíràn fún èèlò lásán.
22 Bẹ́ẹ̀ náà ni ohun tí Ọlọrun ṣe rí. Ó wù ú láti fi ibinu ati agbára rẹ̀ hàn. Ó wá fi ọ̀pọ̀ sùúrù fara da àwọn tí ó yẹ kí ó fi ibinu parun.
23 Báyìí náà ni ó fi ògo ńlá rẹ̀ hàn pẹlu fún àwọn tí ó ṣàánú fún, àní fún àwa tí ó ti pèsè ọlá sílẹ̀ fún.
24 Àwa náà ni ó pè láti ààrin àwọn Juu ati láti ààrin àwọn tí kìí ṣe Juu pẹlu;
25 bí ó ti sọ ninu Ìwé Hosia pé,“Èmi yóo pe àwọn tí kì í ṣe eniyan mi ní ‘Eniyan mi.’N óo sì pe àwọn orílẹ̀-èdè tí n kò náání ní ‘Àyànfẹ́ mi.’
26 Ní ibìkan náà tí a ti sọ fún wọn rí pé,‘Ẹ kì í ṣe eniyan mi mọ́’ni a óo ti pè wọ́n níọmọ Ọlọrun alààyè.”
27 Aisaya náà kéde nípa Israẹli pé, “Bí àwọn ọmọ Israẹli tilẹ̀ pọ̀ bí iyanrìn òkun, sibẹ díẹ̀ péré ni a óo gbà là.