4 Emi si gbadura si Oluwa Ọlọrun mi, mo si ṣe ijẹwọ mi, mo si wipe, Oluwa, iwọ Ọlọrun ti o tobi, ti o si li ẹ̀ru, ti npa majẹmu ati ãnu mọ́ fun awọn ti o fẹ ẹ, ati fun awọn ti o pa ofin rẹ̀ mọ́;
5 Awa ti ṣẹ̀, awa si ti nda ẹ̀ṣẹ, awa si ti ṣe buburu gidigidi, awa si ti ṣọ̀tẹ, ani nipa kikuro ninu ẹkọ́ rẹ, ati idajọ rẹ:
6 Bẹ̃li awa kò si fi eti si awọn iranṣẹ rẹ, awọn woli, ti o sọ̀rọ li orukọ rẹ fun awọn ọba wa, awọn ọmọ-alade wa, ati awọn baba wa, ati fun gbogbo awọn enia ilẹ wa.
7 Oluwa tirẹ li ododo, ṣugbọn tiwa ni itiju, gẹgẹ bi o ti ri loni; fun awọn enia Juda, ati fun awọn olugbe Jerusalemu, ati fun gbogbo Israeli, ti o sunmọ tosi, ati awọn ti o jina rére; ni gbogbo ilẹkilẹ, nibiti o gbe ti le wọn rè, nitori ẹ̀ṣẹ wọn ti nwọn ti ṣẹ̀ si ọ.
8 Oluwa, tiwa ni itiju, ti awọn ọba wa, ati awọn olori wa, ati ti awọn baba wa, nitori ti awa ti ṣọ̀tẹ si ọ.
9 Sibẹ ti Oluwa Ọlọrun wa li ãnu ati idariji bi awa tilẹ ṣọ̀tẹ si i;
10 Bẹ̃li awa kò si gbà ohùn Oluwa Ọlọrun wa gbọ́, lati ma rìn nipa ofin ti o gbé kalẹ niwaju wa lati ọwọ awọn iranṣẹ rẹ̀, awọn woli wá.