1 Ọ̀RỌ Oluwa ti o tọ̀ Hosea, ọmọ Beeri wá, li ọjọ Ussiah, Jotamu, Ahasi, ati Hesekiah, awọn ọba Juda, ati li ọjọ Jeroboamu ọmọ Joaṣi, ọba Israeli.
2 Ibẹ̀rẹ ọ̀rọ Oluwa si Hosea. Oluwa si wi fun Hosea, pe, Lọ, fẹ́ agbère obinrin kan fun ara rẹ, ati awọn ọmọ agbère; nitori ilẹ yi ti ṣe agbère gidigidi, kuro lẹhin Oluwa.
3 O si lọ o si fẹ́ Gomeri ọmọbinrin Diblaimu; ẹniti o loyún, ti o si bi ọmọkunrin kan fun u.
4 Oluwa si wi fun u pe, Pè orukọ rẹ̀ ni Jesreeli; nitori niwọ̀n igbà diẹ, emi o bẹ̀ ẹ̀jẹ Jesreeli wò li ara ile Jehu, emi o si mu ki ijọba ile Israeli kasẹ̀.
5 Yio si ṣe li ọjọ na, li emi o ṣẹ́ ọrun Israeli ni afonifojì Jesreeli.
6 O si tún loyún, o si bi ọmọbinrin kan. Ọlọrun si wi fun u pe, Pè orukọ rẹ̀ li Loruhama: nitori emi kì yio tún ma ṣãnu fun ile Israeli mọ, nitoriti emi o mu wọn kuro.
7 Ṣugbọn emi o ṣãnu fun ile Juda, emi o si fi Oluwa Ọlọrun wọn gbà wọn là, emi kì yio si fi ọrun, tabi idà, tabi ogun, ẹṣin, tabi ẹlẹṣin gbà wọn là.
8 Nigbati o gbà ọmu li ẹnu Loruhama, o si loyún o si bi ọmọkunrin kan.
9 Nigbana ni Ọlọrun wipe, Pè orukọ rẹ̀ ni Loammi; nitori ẹnyin kì iṣe enia mi, emi kì yio si ṣe Ọlọrun nyin.
10 Ṣugbọn iye awọn ọmọ Israeli yio ri bi iyanrìn okun, ti a kò le wọ̀n ti a kò si lè ikà; yio si ṣe, ni ibi ti a gbe ti wi fun wọn pe, Ẹnyin kì iṣe enia mi, ibẹ̀ li a o gbe wi fun wọn pe, Ẹnyin li ọmọ Ọlọrun alãyè.
11 Nigbana ni a o kó awọn ọmọ Juda ati awọn ọmọ Israeli jọ̀ pọ̀, nwọn o si yàn olori kan fun ara wọn, nwọn o si jade kuro ni ilẹ na: nitori nla ni ọjọ Jesreeli yio jẹ.