Hos 7 YCE

1 NIGBATI emi iba mu Israeli li ara dá, nigbana ni ẹ̀ṣẹ Efraimu fi ara hàn, ati ìwa-buburu Samaria; nitori nwọn ṣeké; olè si wọle, ọwọ́ olè si nkoni lode.

2 Nwọn kò si rò li ọkàn wọn pe, emi ranti gbogbo ìwa-buburu wọn: nisisiyi iṣẹ ara wọn duro yi wọn ka; nwọn wà niwaju mi.

Ọ̀tẹ̀ ní Ààfin

3 Nwọn fi ìwa-buburu wọn mu ki ọba yọ̀; nwọn si fi eké wọn mu awọn ọmọ-alade yọ̀.

4 Gbogbo nwọn ni panṣagà, bi ãrò ti alakàra mu gboná, ti o dawọ́ kikoná duro, lẹhìn igbati o ti pò iyẹ̀fun tan, titi yio fi wú.

5 Li ọjọ ọba wa, awọn ọmọ-alade ti fi oru ọti-waini mu u ṣaisàn; o nà ọwọ́ rẹ̀ jade pẹlu awọn ẹlẹgàn.

6 Nitori nwọn ti mura ọkàn wọn silẹ bi ãrò, nigbati nwọn ba ni buba: alakàra wọn sùn ni gbogbo oru; li owurọ̀ o jo bi ọwọ́-iná.

7 Gbogbo wọn gboná bi ãrò, nwọn ti jẹ awọn onidajọ wọn run; gbogbo ọba wọn ṣubu: kò si ẹnikan ninu wọn ti o ke pè mi.

Israẹli ati Àwọn Orílẹ̀-Èdè

8 Efraimu, on ti dà ara rẹ̀ pọ̀ mọ awọn enia na; Efraimu ni akàra ti a kò yipadà.

9 Awọn alejò ti jẹ agbara rẹ̀ run, on kò si mọ̀: nitõtọ, ewú wà kakiri li ara rẹ̀, sibẹ̀ on kò mọ̀.

10 Igberaga Israeli si njẹri si i li oju rẹ̀; nwọn kò si yipadà si Oluwa Ọlọrun wọn, bẹ̃ni fun gbogbo eyi nwọn kò si wá a.

11 Efraimu pẹlu dabi òpe adàba ti kò li ọkàn; nwọn kọ si Egipti, nwọn lọ si Assiria.

12 Nigbati nwọn o lọ, emi o nà àwọn mi le wọn; emi o mu wọn wá ilẹ bi ẹiyẹ oju-ọrun; emi o nà wọn, bi ijọ-enia wọn ti gbọ́.

13 Egbe ni fun wọn! nitori nwọn ti sá kuro lọdọ mi: iparun ni fun wọn! nitori nwọn ti ṣẹ̀ si mi: bi o tilẹ ṣepe mo ti rà wọn padà, ṣugbọn nwọn ti ṣe eké si mi.

14 Nwọn kò si ti fi tọkàntọkàn ké pè mi, nigbati nwọn hu lori akete wọn: nwọn kó ara wọn jọ fun ọkà ati ọti-waini, nwọn si ṣọ̀tẹ si mi.

15 Bi mo ti dì, ti mo si fun apa wọn li okun, sibẹ̀ nwọn nrò ibi si mi.

16 Nwọn yipadà, ṣugbọn kì iṣe si Ọga-ogo: nwọn dàbi ọrun ẹtàn; awọn ọmọ-alade wọn yio tipa idà ṣubu, nitori irúnu ahọn wọn: eyi ni yio ṣe ẹsín wọn ni ilẹ Egipti.

orí

1 2 3 4 5 6 7 8 9 10 11 12 13 14