Hos 8 YCE

OLUWA Bá Israẹli Wí nítorí Ìwà Ìbọ̀rìṣà

1 FI ipè si ẹnu rẹ. Yio wá bi idì si ile Oluwa, nitori nwọn ti re majẹmu mi kọja, nwọn si ti rú ofin mi.

2 Nwọn o kigbe si mi pe, Ọlọrun mi, awa Israeli mọ̀ ọ.

3 Israeli ti gbe ohunrere sọnù; ọta yio lepa rẹ̀.

4 Nwọn ti fi ọba jẹ, ṣugbọn kì iṣe nipasẹ̀ mi: nwọn ti jẹ olori, ṣugbọn emi kò si mọ̀: fàdakà wọn ati wurà wọn ni nwọn fi ṣe òriṣa fun ara wọn, ki a ba le ké wọn kuro.

5 Ọmọ-malu rẹ ti ta ọ nù, Samaria; ibinu mi rú si wọn: yio ti pẹ to ki nwọn to de ipò ailẹ̀ṣẹ?

6 Nitori lati ọdọ Israeli wá li o ti ri bẹ̃ pẹlu; oniṣọ̀na li o ṣe e; nitorina on kì iṣe Ọlọrun: ṣugbọn ọmọ malu Samaria yio fọ tũtũ.

7 Nitori nwọn ti gbìn ẹfũfũ, nwọn o si ka ãjà: kò ni igi ọka: irúdi kì yio si mu onjẹ wá: bi o ba ṣepe o mu wá, alejò yio gbe e mì.

8 A gbe Israeli mì: nisisiyi ni nwọn o wà lãrin awọn Keferi bi ohun-elò ninu eyiti inu-didùn kò si.

9 Nitori nwọn goke lọ si Assiria, kẹtẹ́kẹtẹ́ igbẹ́ nikan fun ara rẹ̀: Efraimu ti bẹ̀ awọn ọrẹ li ọ̀wẹ.

10 Nitõtọ, bi nwọn tilẹ ti bẹ̀ ọ̀wẹ lãrin awọn orilẹ-ède, nisisiyi li emi o ko wọn jọ, nwọn o si kãnu diẹ fun ẹrù ọba awọn ọmọ-alade.

11 Nitori Efraimu ti tẹ́ pẹpẹ pupọ̀ lati dẹ̀ṣẹ, pẹpẹ yio jẹ ohun atidẹ̀ṣẹ fun u.

12 Mo ti kọwe ohun pupọ̀ ti ofin mi si i, ṣugbọn a kà wọn si bi ohun ajèji.

13 Nwọn rubọ ẹran ninu ẹbọ ẹran mi, nwọn si jẹ ẹ; Oluwa kò tẹwọgbà wọn; nisisiyi ni yio ránti ìwa-buburu wọn, yio si bẹ̀ ẹ̀ṣẹ wọn wò: nwọn o padà lọ si Egipti.

14 Nitori Israeli ti gbagbe Ẹlẹda rẹ̀, o si kọ́ tempili pupọ; Juda si ti sọ ilu olodi di pupọ̀: ṣugbọn emi o rán iná kan si ori awọn ilu rẹ̀, yio si jẹ awọn ãfin rẹ̀ wọnni run.

orí

1 2 3 4 5 6 7 8 9 10 11 12 13 14