1 NIGBATI Efraimu sọ̀rọ, ìwarìri ni; o gbe ara rẹ̀ ga ni Israeli; ṣugbọn nigbati o ṣẹ̀ ninu Baali, o kú.
2 Nisisiyi, nwọn si dá ẹ̀ṣẹ kún ẹ̀ṣẹ, nwọn si ti fi fàdakà wọn ṣe ere didà fun ara wọn, ati òriṣa ìmọ wọn: iṣẹ oniṣọnà ni gbogbo rẹ̀; nwọn wi niti wọn pe, Jẹ ki awọn enia ti nrubọ fi ẹnu kò awọn ọmọ malu li ẹnu.
3 Nitorina ni nwọn o ṣe dabi kũkũ owurọ̀, ati bi irì owurọ̀ ti nkọja lọ, bi iyangbò ti a ti ọwọ́ ijì gbá kuro ninu ilẹ ipakà, ati bi ẹ̃fin ti ijade kuro ninu ile ẹ̃fin.
4 Ṣugbọn emi li Oluwa Ọlọrun rẹ lati ilẹ Egipti wá, iwọ kì yio si mọ̀ ọlọrun kan bikòṣe emi: nitori kò si olugbàla kan lẹhìn mi.
5 Emi ti mọ̀ ọ li aginjù, ni ilẹ ti o pongbẹ.
6 Gẹgẹ bi a ti bọ́ wọn, bẹ̃ni nwọn yó; nwọn yó, nwọn si gbe ọkàn wọn ga; nitorina ni nwọn ṣe gbagbe mi.
7 Nitorina li emi o ṣe dabi kiniun si wọn; emi o si ma ṣọ wọn bi ẹkùn li ẹ̀ba ọ̀na.
8 Emi o pade wọn bi beari ti a gbà li ọ̀mọ, emi o si fà àwọn ọkàn wọn ya, nibẹ̀ ni emi o si jẹ wọn run bi kiniun, ẹranko igbẹ ni yio fà wọn ya.
9 Israeli, iwọ ti pa ara rẹ run, niti pe iwọ wà lodi si emi, irànlọwọ rẹ.
10 Nibo li ọba rẹ gbe wà nisisiyi ninu gbogbo ilu rẹ, ti o le gbà ọ? ati awọn onidajọ rẹ, niti awọn ti iwọ wipe; Fun mi li ọba ati awọn ọmọ-alade.
11 Emi fun ọ li ọba ni ibinu mi, mo si mu u kuro ni irúnu mi.
12 A dì aiṣedẽde Efraimu; ẹ̀ṣẹ rẹ̀ pamọ.
13 Irora obinrin ti nrọbi yio de si i: alaigbọn ọmọ li on; nitori on kò duro li akokò si ibi ijade ọmọ.
14 Emi o rà wọn padà lọwọ agbara isà-okú; Emi o rà wọn padà lọwọ ikú; Ikú, ajàkalẹ arùn rẹ dà? Isà-okú, iparun rẹ dà? ironupiwàda yio pamọ kuro loju mi.
15 Bi on tilẹ ṣe eleso ninu awọn arakunrin rẹ̀, afẹfẹ́ ilà-õrùn kan yio de, afẹ̃fẹ́ Oluwa yio ti aginjù wá, orisun rẹ̀ yio si gbẹ, ati oju isun rẹ̀ li a o mu gbẹ: on o bà ohun elò daradara gbogbo jẹ.
16 Samaria yio di ahoro: nitoriti on ti ṣọ̀tẹ si Ọlọrun rẹ̀: nwọn o ti ipa idà ṣubu: a o fọ́ ọmọ wọn tũtũ, ati aboyún wọn li a o là ni inu.