Hos 12 YCE

1 EFRAIMU njẹ afẹfẹ́, o si ntọ̀ afẹfẹ́ ila-õrun lẹhìn: o nmu eke ati iparun pọ̀ si i lojojumọ; nwọn si ba awọn ara Assiria da majẹmu, nwọn si nrù ororo lọ si Egipti.

2 Oluwa ni ẹjọ kan ba Juda rò pẹlu, yio si jẹ Jakobu ni iyà gẹgẹ bi ọ̀na rẹ̀; gẹgẹ bi iṣe rẹ̀ ni yio san padà fun u.

3 O di arakunrin rẹ̀ mu ni gigisẹ̀ ni inu, ati nipa ipá rẹ̀ o ni agbara pẹlu Ọlọrun.

4 Nitõtọ, o ni agbara lori angeli, o si bori: o sọkun, o si bẹ̀bẹ lọdọ rẹ̀: o ri i ni Beteli, nibẹ̀ li o gbe ba wa sọ̀rọ;

5 Ani Oluwa Ọlọrun awọn ọmọ-ogun; Oluwa ni iranti rẹ̀.

6 Nitorina, iwọ yipadà si Ọlọrun rẹ: pa ãnu ati idajọ mọ, ki o si ma duro de Ọlọrun rẹ nigbagbogbo.

Àwọn Ìdájọ́ Mìíràn

7 Kenaani ni, iwọ̀n ẹtàn mbẹ li ọwọ́ rẹ̀: o fẹ lati ninilara.

8 Efraimu si wipe, Ṣugbọn emi di ọlọrọ̀, mo ti ri ini fun ara mi: ninu gbogbo lãlã mi nwọn kì yio ri aiṣedẽde kan ti iṣe ẹ̀ṣẹ lara mi.

9 Ati emi, Oluwa Ọlọrun rẹ lati ilẹ̀ Egipti wá, yio si tún mu ọ gbe inu agọ, bi ọjọ ajọ-ọ̀wọ wọnni.

10 Emi ti sọ̀rọ nipa awọn woli pẹlu, mo si ti mu iran di pupọ̀, mo ti ṣe ọ̀pọlọpọ akàwe, nipa ọwọ́ awọn woli.

11 Aiṣedẽde mbẹ ni Gileadi bi? nitõtọ asan ni nwọn: nwọn rubọ akọ malu ni Gilgali; nitõtọ, pẹpẹ wọn dabi ebè ni aporo oko.

12 Jakobu si salọ si ilẹ Siria: Israeli si sìn nitori aya kan; ati nitori aya kan li o ṣọ agùtan.

13 Ati nipa woli kan ni Oluwa mu Israeli jade ni Egipti: nipa woli kan li a si pa on mọ.

14 Efraimu mu u binu kikorò: nitorina ni yio fi ẹjẹ̀ rẹ̀ si ori rẹ̀, ẹgàn rẹ̀ li Oluwa rẹ̀ yio si san padà fun u.

orí

1 2 3 4 5 6 7 8 9 10 11 12 13 14