1 Ẹ gbọ́ ọ̀rọ Oluwa, ẹnyin ọmọ Israeli; nitori Oluwa ni ẹjọ kan ba awọn ara ilẹ na wi, nitoriti kò si otitọ, tabi ãnu, tabi ìmọ Ọlọrun ni ilẹ na.
2 Nipa ibura, ati eke, ati ipani, ati olè, ati iṣe panṣaga, nwọn gbìjà, ẹ̀jẹ si nkàn ẹ̀jẹ.
3 Nitorina ni ilẹ na yio ṣe ṣọ̀fọ, ati olukuluku ẹniti ngbé inu rẹ̀ yio rọ, pẹlu awọn ẹranko igbẹ, ati pẹlu awọn ẹiyẹ oju ọrun; a o si mu awọn ẹja inu okun kuro pẹlu.
4 Ṣugbọn má jẹ ki ẹnikẹni ki o jà, tabi ki o ba ẹnikeji rẹ̀ wi: nitori awọn enia rẹ dabi awọn ti mba alufa jà.
5 Iwọ o si ṣubu li ọ̀san, woli yio si ṣubu pẹlu rẹ li alẹ, emi o si ké iya rẹ kuro.
6 A ké awọn enia mi kuro nitori aini ìmọ: nitori iwọ ti kọ̀ ìmọ silẹ, emi o si kọ̀ ọ, ti iwọ kì yio ṣe alufa mi mọ: niwọ̀n bi iwọ ti gbagbe ofin Ọlọrun rẹ, emi pẹlu o gbagbe awọn ọmọ rẹ.
7 Bi a ti mu wọn pọ̀ si i to, bẹ̃ na ni nwọn si dẹ̀ṣẹ si mi to: nitorina emi o yi ogo wọn padà si itìju.
8 Nwọn jẹ ẹ̀ṣẹ awọn enia mi, nwọn si gbe ọkàn wọn si aiṣedẽde wọn.
9 Yio si ṣe, gẹgẹ bi enia, bẹ̃li alufa: emi o si bẹ̀ wọn wò nitori ọ̀na wọn, emi o si san èrè iṣẹ wọn padà fun wọn.
10 Nwọn o si jẹ, nwọn kì o si yó: nwọn o ṣe agbère, nwọn kì o si rẹ̀: nitori nwọn ti fi ati-kiyesi Oluwa silẹ.
11 Agbère ati ọti-waini, ati ọti-waini titun a ma gbà enia li ọkàn.
12 Awọn enia mi mbère ìmọ lọwọ igi wọn, ọpá wọn si nfi hàn fun wọn: nitori ẹmi agbère ti mu wọn ṣìna, nwọn si ti ṣe agbère lọ kuro labẹ Ọlọrun wọn.
13 Nwọn rubọ lori awọn oke-nla, nwọn si sun turari lori awọn oke kékèké, labẹ igi oaku ati igi poplari ati igi ẹlmu, nitoriti ojìji wọn dara: nitorina awọn ọmọbinrin nyin yio ṣe agbère, ati awọn afẹ́sọnà nyin yio ṣe panṣagà.
14 Emi kì yio ba awọn ọmọbinrin nyin wi nigbati nwọn ba ṣe agbère, tabi awọn afẹ́sọnà nyin nigbati nwọn ba ṣe panṣagà: nitori nwọn yà si apakan pẹlu awọn agbère, nwọn si mba awọn panṣagà rubọ̀: nitorina awọn enia ti kò ba moye yio ṣubu.
15 Bi iwọ, Israeli, ba ṣe agbère, máṣe jẹ ki Juda ṣẹ̀; ẹ má si wá si Gilgali, bẹ̃ni ki ẹ má si goke lọ si Bet-afeni, bẹ̃ni ki ẹ má si bura pe, Oluwa mbẹ.
16 Nitori Israeli ṣe agidi bi ọmọ malu alagidi; nisisiyi Oluwa yio bọ́ wọn bi ọdọ-agùtan ni ibi ayè nla.
17 Efraimu dapọ̀ mọ òriṣa: jọwọ rẹ̀ si.
18 Ohun mimu wọn di kikan: nwọn ṣe agbère gidigidi; awọn olori rẹ̀ fẹ itìju, ẹ bun u li ayè.
19 Afẹfẹ ti dè e pẹlu mọ iyẹ́ apa rẹ̀, nwọn o si tíju nitori ẹbọ wọn.