3 Nitori nisisiyi ni nwọn o wipe, Awa kò li ọba, nitoriti awa kò bẹ̀ru Oluwa; njẹ kili ọba o ṣe fun wa?
4 Nwọn ti sọ ọ̀rọ, nwọn mbura eke ni didà majẹmu: bayi ni idajọ hù soke bi igi iwọ, ni aporo oko.
5 Nitori awọn ọmọ-malu Bet-afeni, awọn ti ngbe Samaria yio bẹ̀ru: nitori awọn enia ibẹ̀ yio ṣọ̀fọ lori rẹ̀, ati awọn baba-oloriṣà ibẹ̀ ti o yọ̀ lori rẹ̀, nitori ogo rẹ̀, nitori o ti lọ kuro lọdọ rẹ̀.
6 A o si mu u lọ si Assiria pẹlu ẹbùn fun Jarebu ọba: Efraimu yio gbà itiju, oju yio si tì Israeli nitori igbìmọ rẹ̀.
7 Bi o ṣe ti Samaria, a ké ọba rẹ̀ kuro bi ifõfõ loju omi.
8 Ibi giga Afeni pẹlu, ẹ̀ṣẹ Israeli, li a o parun; ẹgún ọ̀gan on oṣuṣu yio hù jade lori pẹpẹ wọn; nwọn o si wi fun awọn oke-nla pe, Bò wa mọlẹ; ati fun awọn oke kékèké pe, Wó lù wa.
9 Lati ọjọ Gibea ni iwọ ti ṣẹ̀, Israeli: nibẹ̀ ni nwọn duro: ogun Gibea si awọn ọmọ ẹ̀ṣẹ kò ha le wọn ba?