9 Lati ọjọ Gibea ni iwọ ti ṣẹ̀, Israeli: nibẹ̀ ni nwọn duro: ogun Gibea si awọn ọmọ ẹ̀ṣẹ kò ha le wọn ba?
10 Ifẹ inu mi ni ki nle nà wọn; a o si gbá awọn enia jọ si wọn, lati di ara wọn si ẹ̀ṣẹ wọn mejeji.
11 Efraimu si dabi ọmọ-malu ti a kọ́, ti o si fẹ́ lati ma tẹ ọkà; ṣugbọn emi rekọja li ori ọrùn rẹ̀ ti o ni ẹwà: emi o mu ki Efraimu gùn ẹṣin; Juda yio tú ilẹ, Jakobu yio si fọ́ ogulùtu rẹ̀.
12 Ẹ furùngbin fun ara nyin li ododo, ẹ ká li ãnu: ẹ tú ilẹ nyin ti a kò ro: nitori o to akokò lati wá Oluwa, titi yio fi de, ti yio si fi rọ̀jo ododo si nyin.
13 Ẹnyin ti tulẹ ìwa-buburu, ẹnyin ti ká aiṣedẽde; ẹnyin ti jẹ eso eke: nitori iwọ gbẹkẹ̀le ọ̀na rẹ, ninu ọ̀pọlọpọ awọn alagbara rẹ.
14 Nitorina li ariwo yio dide ninu awọn enia rẹ, gbogbo awọn odi agbara rẹ li a o si bajẹ, bi Ṣalmani ti ba Bet-abeli jẹ li ọjọ ogun: a fọ́ iya tũtũ lori awọn ọmọ rẹ̀.
15 Bẹ̃ni Beteli yio ṣe si nyin, nitori ìwa-buburu nla nyin; ni kùtukùtu li a o ke ọba Israeli kuro patapata.