9 Emi kì yio mu gbigboná ibinu mi ṣẹ, emi kì yio yipadà lati run Efraimu: nitori Ọlọrun li emi, kì iṣe enia; Ẹni-Mimọ lãrin rẹ: emi kì yio si wá ninu ibinu.
10 Nwọn o ma tẹ̀le Oluwa: on o ke ramùramù bi kiniun: nigbati on o ke, nigbana li awọn ọmọ yio wariri lati iwọ-õrun wá.
11 Nwọn o warìri bi ẹiyẹ lati Egipti wá, ati bi adàba lati ilẹ Assiria wá: emi o si fi wọn si ile wọn, li Oluwa wi.
12 Efraimu fi eke sagbàra yi mi ka, ile Israeli si fi ẹtàn sagbàra yi mi ka: ṣugbọn Juda njọba sibẹ̀ pẹlu Ọlọrun, o si ṣe olõtọ pẹlu Ẹni-mimọ́.