1 EFRAIMU njẹ afẹfẹ́, o si ntọ̀ afẹfẹ́ ila-õrun lẹhìn: o nmu eke ati iparun pọ̀ si i lojojumọ; nwọn si ba awọn ara Assiria da majẹmu, nwọn si nrù ororo lọ si Egipti.
2 Oluwa ni ẹjọ kan ba Juda rò pẹlu, yio si jẹ Jakobu ni iyà gẹgẹ bi ọ̀na rẹ̀; gẹgẹ bi iṣe rẹ̀ ni yio san padà fun u.
3 O di arakunrin rẹ̀ mu ni gigisẹ̀ ni inu, ati nipa ipá rẹ̀ o ni agbara pẹlu Ọlọrun.
4 Nitõtọ, o ni agbara lori angeli, o si bori: o sọkun, o si bẹ̀bẹ lọdọ rẹ̀: o ri i ni Beteli, nibẹ̀ li o gbe ba wa sọ̀rọ;
5 Ani Oluwa Ọlọrun awọn ọmọ-ogun; Oluwa ni iranti rẹ̀.
6 Nitorina, iwọ yipadà si Ọlọrun rẹ: pa ãnu ati idajọ mọ, ki o si ma duro de Ọlọrun rẹ nigbagbogbo.