1 Ẹ wi fun awọn arakunrin nyin, Ammi; ati fun awọn arabinrin nyin, Ruhama.
2 Ẹ ba iya nyin wijọ, ẹ wijọ; nitori on kì iṣe aya mi, bẹ̃ni emi kì iṣe ọkọ rẹ̀: nitori na jẹ ki on ki o mu gbogbo agberè rẹ̀ kuro ni iwaju rẹ̀, ati gbogbo panṣaga rẹ̀ kuro larin ọyàn rẹ̀.
3 Ki emi má ba tú u si ihòho, emi o si gbe e kalẹ bi ọjọ ti a bi i, emi o si ṣe e bi ijù, emi o si gbe e kalẹ bi ilẹ gbigbẹ, emi o si fi ongbẹ pa a kú.
4 Emi kì yio si ṣãnu fun awọn ọmọ rẹ̀; nitoriti nwọn jẹ́ ọmọ agbère.
5 Nitoriti iya wọn ti hùwa agbère: ẹniti o loyun wọn ti ṣe ohun itiju: nitori ti o wipe, Emi o tun tọ̀ awọn ayànfẹ́ mi lẹhìn, ti nfun mi ni onjẹ mi ati omi mi, irun agùtan mi ati ọgbọ̀ mi, ororo mi, ati ohun mimu mi.
6 Nitorina kiyesi i, emi o fi ẹgún sagbàra yi ọ̀na rẹ̀ ka, emi o si mọ odi, ti on kì yio fi ri ọ̀na rẹ̀ mọ.
7 On o si lepa awọn ayànfẹ́ rẹ̀, ṣugbọn kì yio le ba wọn; on o si wá wọn, ṣugbọn kì yio ri wọn: nigbana ni yio wipe, Emi o padà tọ̀ ọkọ mi iṣãju lọ; nitoriti o sàn fun mi nigbana jù ti isisiyi lọ.