1 OLUWA sí wi fun mi pe, Tun lọ, fẹ́ obinrin kan ti iṣe olùfẹ́ ọrẹ rẹ̀, ati panṣagà, gẹgẹ bi ifẹ Oluwa si awọn ọmọ Israeli, ti nwò awọn ọlọrun miràn, ti nwọn si nfẹ́ akàra eso àjara.
2 Bẹ̃ni mo rà a fun ara mi ni fadakà mẹ̃dogun, ati homeri barli kan pẹlu ãbọ̀:
3 Mo si wi fun u pe, Iwọ o ba mi gbe li ọjọ pupọ̀; iwọ kì yio si hùwa agbère, iwọ kì yio si jẹ ti ọkunrin miràn: bẹ̃li emi o jẹ tirẹ pẹlu.
4 Nitori ọjọ pupọ̀ li awọn ọmọ Israeli yio gbe li aini ọba, ati li aini olori, ati li aini ẹbọ, li aini ere, ati li aini awòaiyà, ati li aini tẹrafimu.