2 Bẹ̃ni mo rà a fun ara mi ni fadakà mẹ̃dogun, ati homeri barli kan pẹlu ãbọ̀:
3 Mo si wi fun u pe, Iwọ o ba mi gbe li ọjọ pupọ̀; iwọ kì yio si hùwa agbère, iwọ kì yio si jẹ ti ọkunrin miràn: bẹ̃li emi o jẹ tirẹ pẹlu.
4 Nitori ọjọ pupọ̀ li awọn ọmọ Israeli yio gbe li aini ọba, ati li aini olori, ati li aini ẹbọ, li aini ere, ati li aini awòaiyà, ati li aini tẹrafimu.
5 Lẹhìn na awọn ọmọ Israeli yio padà, nwọn o si wá Oluwa Ọlọrun wọn, ati Dafidi ọba wọn; nwọn o si bẹ̀ru Oluwa, ati ore rẹ̀ li ọjọ ikẹhìn.