1 Ẹ gbọ́ ọ̀rọ Oluwa, ẹnyin ọmọ Israeli; nitori Oluwa ni ẹjọ kan ba awọn ara ilẹ na wi, nitoriti kò si otitọ, tabi ãnu, tabi ìmọ Ọlọrun ni ilẹ na.
2 Nipa ibura, ati eke, ati ipani, ati olè, ati iṣe panṣaga, nwọn gbìjà, ẹ̀jẹ si nkàn ẹ̀jẹ.
3 Nitorina ni ilẹ na yio ṣe ṣọ̀fọ, ati olukuluku ẹniti ngbé inu rẹ̀ yio rọ, pẹlu awọn ẹranko igbẹ, ati pẹlu awọn ẹiyẹ oju ọrun; a o si mu awọn ẹja inu okun kuro pẹlu.
4 Ṣugbọn má jẹ ki ẹnikẹni ki o jà, tabi ki o ba ẹnikeji rẹ̀ wi: nitori awọn enia rẹ dabi awọn ti mba alufa jà.
5 Iwọ o si ṣubu li ọ̀san, woli yio si ṣubu pẹlu rẹ li alẹ, emi o si ké iya rẹ kuro.
6 A ké awọn enia mi kuro nitori aini ìmọ: nitori iwọ ti kọ̀ ìmọ silẹ, emi o si kọ̀ ọ, ti iwọ kì yio ṣe alufa mi mọ: niwọ̀n bi iwọ ti gbagbe ofin Ọlọrun rẹ, emi pẹlu o gbagbe awọn ọmọ rẹ.