12 Nitorina ni emi o ṣe dabi kòkoro aṣọ si Efraimu, ati si ile Juda bi idin.
13 Nigbati Efraimu ri arùn rẹ̀, ti Juda si ri ọgbẹ́ rẹ̀, nigbana ni Efraimu tọ̀ ara Assiria lọ, o si ranṣẹ si ọba Jarebu; ṣugbọn on kò le mu ọ lara da, bẹ̃ni kò le wò ọgbẹ́ rẹ jiná.
14 Nitori emi o dàbi kiniun si Efraimu, ati bi ọmọ kiniun si ile Juda, emi, ani emi o fàya, emi o si lọ, emi o mu lọ, ẹnikẹni kì yio si gbà a silẹ.
15 Emi o padà lọ si ipò mi, titi nwọn o fi jẹwọ ẹ̀ṣẹ wọn, ti nwọn o si wá oju mi: ninu ipọnju wọn, nwọn o wá mi ni kùtukùtu.