2 Ahasiah si ṣubu lãrin fèrese ọlọnà kan ni iyara òke rẹ̀ ti o wà ni Samaria, o si ṣàisan: o si rán awọn onṣẹ o si wi fun wọn pe, Ẹ lọ, ẹ bère lọwọ Baalsebubu, oriṣa Ekroni, bi emi o là ninu aisan yi.
3 Ṣugbọn angeli Oluwa wi fun Elijah, ara Tiṣbi pe, Dide, gòke lọ ipade awọn onṣẹ ọba Samaria, ki o si wi fun wọn pe, Kò ṣe pe nitoriti kò si Ọlọrun ni Israeli, ni ẹnyin fi nlọ ibère lọwọ Baalsebubu oriṣa Ekroni?
4 Njẹ nitorina bayi li Oluwa wi, Iwọ kì o sọ̀kalẹ kuro lori akete nì lori eyiti iwọ ti gùn, ṣugbọn kikú ni iwọ o kú. Elijah si lọ kuro.
5 Nigbati awọn onṣẹ si pada si ọdọ rẹ̀, o wi fun wọn pe, Ẽṣe ti ẹnyin fi pada sẹhin?
6 Nwọn si wi fun u pe, Ọkunrin kan li o gòke lati pade wa, o si wi fun wa pe, Ẹ lọ, ẹ pada tọ̀ ọba ti o rán nyin, ki ẹ si wi fun u pe, Bayi li Oluwa wi, kò ṣepe nitoriti kò si Ọlọrun ni Israeli, ni iwọ fi ranṣẹ lọ ibère lọwọ Baalsebubu oriṣa Ekroni? nitorina, iwọ kì o sọ̀kalẹ kuro lori akete nì ti iwọ ti gùn, ṣugbọn kikú ni iwọ o kú.
7 On si wi fun wọn pe, Iru ọkunrin wo li ẹniti o gòke lati pade nyin, ti o si sọ̀rọ wọnyi fun nyin?
8 Nwọn si da a li ohùn pe, Ọkunrin Onirum li ara ni; o si dì àmure awọ mọ́ ẹgbẹ́ rẹ̀. On si wipe, Elijah ara Tiṣbi ni.