2. A. Ọba 19 YCE

Ọba Bèèrè Ìmọ̀ràn Lọ́wọ́ Aisaya

1 O si ṣe, nigbati Hesekiah ọba gbọ́, o si fà aṣọ rẹ̀ ya, o si fi aṣọ ọ̀fọ bò ara rẹ̀, o si lọ sinu ile Oluwa.

2 O si rán Eliakimu, ti iṣe olori ile, ati Ṣebna akọwe, ati awọn àgba alufa, ti nwọn fi aṣọ ọ̀fọ bò ara, sọdọ Isaiah woli ọmọ Amosi.

3 Nwọn si wi fun u pe, Bayi ni Hesekiah wi, Ọjọ oni ọjọ wàhala ni, ati ti ibawi, ati ẹgàn: nitoriti awọn ọmọ de oju-ibí, kò si si agbara lati bi.

4 Bọya Oluwa Ọlọrun rẹ yio gbọ́ gbogbo ọ̀rọ Rabṣake ẹniti ọba Assiria oluwa rẹ̀ ti rán lati kẹgàn Ọlọrun alãyè, yio si ba a wi nitori ọ̀rọ ti Oluwa Ọlọrun rẹ ti gbọ́: njẹ nitorina, gbé adura rẹ soke fun awọn iyokù ti o kù.

5 Bẹ̃li awọn iranṣẹ Hesekiah ọba wá sọdọ Isaiah.

6 Isaiah si wi fun wọn pe, Bayi ni ki ẹ sọ fun oluwa nyin, Bayi li Oluwa wi pe, Máṣe bẹ̀ru ọ̀rọ wọnni, ti o ti gbọ́, ti awọn iranṣẹ ọba Assiria fi sọ ọ̀rọ odi si mi.

7 Kiyesi i, emi o rán ẽmi kan si i, on o si gbọ́ ariwo, yio si pada si ilẹ on tikalarẹ̀; emi o si mu u ti ipa idà ṣubu ni ilẹ on tikalarẹ̀.

Àwọn ará Asiria tún ranṣẹ ìhàlẹ̀ mìíràn

8 Bẹ̃ni Rabṣake pada, o si ba ọba Assiria mba Libna jagun: nitoriti o ti gbọ́ pe o ti lọ kuro ni Lakiṣi.

9 Nigbati o si gburo Tirhaka ọba Etiopia, pe, Kiyesi i, o jade wá lati ba ọ jagun; o si tun rán awọn onṣẹ si ọdọ Hesekiah wipe,

10 Bayi li ẹnyin o sọ fun Hesekiah ọba Juda, wipe, Máṣe jẹ ki Ọlọrun rẹ, ẹniti iwọ gbẹkẹle ki o tàn ọ jẹ, wipe, A kì yio fi Jerusalemu le ọwọ ọba Assiria.

11 Kiyesi i, iwọ ti gbọ́ ohun ti awọn ọba Assiria ti ṣe si gbogbo ilẹ, ni pipa wọn run patapata: a o ha si gbà iwọ bi?

12 Oriṣa awọn orilẹ-ède ha gbà awọn ti awọn baba mi ti parun; bi Gosani, ati Harani, ati Resefu, ati awọn ọmọ Edeni ti o wà ni Telassari?

13 Nibo li ọba Hamati, ati ọba Arpadi, ati ọba ilu Sefarfaimu, ti Hena, ati Ifa gbe wà?

14 Hesekiah si gbà iwe na lọwọ awọn onṣẹ na, o si kà a: Hesekiah si gòke lọ sinu ile Oluwa, o si tẹ́ ẹ siwaju Oluwa.

15 Hesekiah si gbadura niwaju Oluwa, o si wipe: Oluwa Ọlọrun Israeli, ti ngbe ãrin awọn kerubu, iwọ li Ọlọrun, ani iwọ nikanṣoṣo, ninu gbogbo awọn ilẹ-ọba aiye; iwọ li o dá ọrun on aiye.

16 Dẹti rẹ silẹ Oluwa, ki o si gbọ́; ṣi oju rẹ, Oluwa, ki o si wò: ki o si gbọ́ ọ̀rọ Sennakeribu ti o rán lati kẹgàn Ọlọrun alãyè.

17 Lõtọ ni, Oluwa, awọn ọba Assiria ti pa awọn orilẹ-ède run ati ilẹ wọn.

18 Nwọn si ti gbe òriṣa wọn sọ sinu iná; nitoriti nwọn kì iṣe ọlọrun, bikòṣe iṣẹ ọwọ enia, igi ati okuta: nitorina ni nwọn ṣe pa wọn run.

19 Njẹ nitorina, Oluwa Ọlọrun wa, emi mbẹ̀ ọ, gbà wa lọwọ rẹ̀, ki gbogbo ilẹ ọba aiye le mọ̀ pe iwọ Oluwa iwọ nikanṣoṣo ni Ọlọrun.

Iṣẹ́ Tí Aisaya Rán sí Ọba

20 Nigbana ni Isaiah ọmọ Amosi ranṣẹ si Hesekiah wipe, Bayi li Oluwa Ọlọrun Israeli wi pe, adura ti iwọ ti gbà si mi si Sennakeribu ọba Assiria emi ti gbọ́.

21 Eyi li ọ̀rọ ti Oluwa ti sọ niti rẹ̀; Wundia ọmọbinrin Sioni ti kẹgàn rẹ, o si ti fi ọ rẹrin ẹlẹyà; ọmọbinrin Jerusalemu ti mì ori rẹ̀ si ọ.

22 Tani iwọ sọ̀rọ buburu si ti iwọ si kẹgàn? ati tani iwọ gbé ohùn rẹ si òke si, ti iwọ gbé oju rẹ ga si òke? ani si Ẹni-Mimọ Israeli.

23 Nipa awọn onṣẹ rẹ, iwọ ti sọ̀rọ buburu si Oluwa, ti nwọn si wipe, Ọpọlọpọ kẹkẹ́ mi li emi fi de ori awọn òke-nla, si ori Lebanoni, emi o si ké igi kedari giga rẹ̀ lulẹ, ati ãyò igi firi rẹ̀; emi o si lọ si ori òke ibùwọ rẹ̀, sinu igbó Karmeli rẹ̀.

24 Emi ti wà kànga, emi si ti mu ajèji omi, atẹlẹsẹ̀ mi li emi si ti fi gbẹ gbogbo odò Egipti.

25 Iwọ kò ti gbọ́, lailai ri emi ti ṣe e, nigba atijọ emi si ti mura tẹlẹ nisisiyi emi ti mu u ṣẹ, ki iwọ ki o le mã sọ ilu olodi wọnni di ahoro, ani di òkiti àlapa.

26 Nitorina ni awọn olugbe wọn fi ṣe alainipa, a daiyàfo wọn nwọn si dãmu; nwọn dàbi koriko igbẹ́, ati bi ewebẹ̀ tutù, bi koriko li ori ile, ati bi ọkà ti o rẹ̀ danù ki o to dàgba soke.

27 Ṣugbọn emi mọ̀ ijoko rẹ, ati ijadelọ rẹ, ati bibọ̀ rẹ, ati ikannu rẹ si mi.

28 Nitori ikánnu rẹ si mi ati irera rẹ de eti mi, nitorina li emi o fi ìwọ̀ mi kọ́ ọ ni imu, ati ijanu mi si ẹnu rẹ, emi o si yi ọ pada si ọ̀na na ti iwọ ti ba wá.

29 Eyi ni yio si ṣe àmi fun ọ, Ẹ jẹ ilalẹ̀hu li ọdun ni, ati li ọdun keji eyiti o hù ninu ọkanna; ati li ọdun kẹta ẹ fun irúgbìn, ki ẹ si kore, ki ẹ si gbìn ọgba ajara, ki ẹ si jẹ eso rẹ̀.

30 Iyokù ile Juda ti o salà yio si tún ta gbòngbo si isàlẹ, yio si so eso li òke.

31 Nitori lati Jerusalemu li awọn iyokù yio jade lọ, ati awọn ti o salà lati oke Sioni jade: itara Oluwa awọn ọmọ-ogun ni yio ṣe eyi.

32 Nitori bayi li Oluwa wi niti ọba Assiria, On kì yio wá si ilu yi, bẹ̃ni kì yio ta ọfà kan sibẹ, kì yio mu asà wá iwaju rẹ̀, bẹ̃ni kì yio mọ odi tì i yika.

33 Ọna na ti o ba wá, ọkanna ni yio ba pada lọ, kì yio si wá si ilu yi, li Oluwa wi.

34 Nitori emi o da abò bò ilu yi, lati gbà a, nitori ti emi tikara mi, ati nitori ti Dafidi iranṣẹ mi.

35 O si ṣe li oru na ni angeli Oluwa jade lọ, o si pa ọkẹ́ mẹsan le ẹgbẹ̃dọgbọn enia ni ibùbo awọn ara Assiria: nigbati nwọn si dide ni kutukutu owurọ, kiyesi i, okú ni gbogbo wọn jasi.

36 Bẹ̃ni Sennakeribu ọba Assiria mu ọ̀na rẹ̀ pọ̀n, o si lọ, o si pada, o si joko ni Ninefe.

37 O si ṣe, bi o ti mbọ̀riṣa ni ile Nisroku oriṣa rẹ̀, ni Adrammeleki ati Ṣareseri awọn ọmọ rẹ̀ fi idà pa a: nwọn si sa lọ si ilẹ Armenia. Esarhaddoni ọmọ rẹ̀ sì jọba ni ipò rẹ̀.

orí

1 2 3 4 5 6 7 8 9 10 11 12 13 14 15 16 17 18 19 20 21 22 23 24 25