1 LI ọdun kẹtadilọgbọ̀n Jeroboamu ọba Israeli ni Asariah (Ussiah) ọmọ Amasiah ọba Juda bẹ̀rẹ si ijọba.
2 Ẹni ọdun mẹrindilogun li on iṣe nigbati o bẹ̀rẹ si ijọba, o si jọba ọdun mejilelãdọta ni Jerusalemu. Orukọ iya rẹ̀ a ma jẹ Jekoliah ti Jerusalemu.
3 O si ṣe eyiti o tọ loju Oluwa, gẹgẹ bi gbogbo eyiti baba rẹ̀ Amasiah ti ṣe;
4 Kiki ibi giga wọnni ni a kò mu kuro: awọn enia nrubọ, nwọn si nsun turari sibẹ ni ibi giga wọnni.
5 Oluwa si kọlù ọba na, bẹ̃li o di adẹtẹ̀ titi di ọjọ ikú rẹ̀, o si ngbe ile ihámọ: Jotamu ọmọ ọba si wà lori ile na, o nṣe idajọ awọn enia ilẹ na.
6 Ati iyokù iṣe Asariah, ati ohun gbogbo ti o ṣe, a kò ha kọ wọn sinu iwe ọ̀rọ ọjọ awọn ọba Juda?
7 Asariah si sùn pẹlu awọn baba rẹ̀; nwọn si sìn i pẹlu awọn baba rẹ̀, ni ilu Dafidi: Jotamu ọmọ rẹ̀ si jọba ni ipò rẹ̀.
8 Li ọdun kejidilogoji Asariah ọba Juda ni Sakariah ọmọ Jeroboamu jọba lori Israeli ni Samaria li oṣù mẹfa.
9 O si ṣe eyi ti o buru li oju Oluwa, bi awọn baba rẹ̀ ti ṣe: on kò kuro ninu ẹ̀ṣẹ Jeroboamu ọmọ Nebati, ẹniti o mu Israeli ṣẹ̀.
10 Ṣallumu ọmọ Jabeṣi si dì rikiṣi si i, o si kọlù u niwaju awọn enia, o si pa a, o si jọba ni ipò rẹ̀.
11 Ati iyokù iṣe Sakariah, kiyesi i, a kọ wọn sinu iwe ọ̀rọ ọjọ awọn ọba Israeli.
12 Eyi li ọ̀rọ Oluwa ti o ti sọ fun Jehu wipe, Awọn ọmọ rẹ iran kẹrin yio joko lori itẹ Israeli, bẹ̃li o si ri.
13 Ṣallumu ọmọ Jabeṣi bẹ̀rẹ si ijọba li ọdun kọkandilogoji Ussiah ọba Juda; o si jọba oṣù kan gbáko ni Samaria.
14 Nitoriti Menahemu ọmọ Gadi gòke lati Tirsa lọ, o si wá si Samaria, o si kọlù Ṣallumi ọmọ Jabeṣi ni Samaria, o si pa a, o si jọba ni ipò rẹ̀.
15 Ati iyokù iṣe Ṣallumu, ati rikiṣi rẹ̀ ti o dì, kiyesi i, a kọ wọn sinu iwe ọ̀rọ ọjọ awọn ọba Israeli.
16 Nigbana ni Menahemu kọlù Tifsa, ati ohun gbogbo ti mbẹ ninu rẹ̀, ati ilẹ agbègbe rẹ̀ wọnni lati Tifsa lọ: nitoriti nwọn kò ṣi i silẹ fun u, nitorina li o ṣe kọlù u; ati gbogbo awọn obinrin aboyun inu rẹ̀ li o là ni inu.
17 Li ọdun kọkandilogoji Asariah ọba Juda ni Menahemu ọmọ Gadi bẹ̀rẹ si ijọba lori Israeli, o si jọba ọdun mẹwa ni Samaria.
18 O si ṣe eyi ti o buru li oju Oluwa: on kò si lọ kuro ninu ẹ̀ṣẹ Jeroboamu ọmọ Nebati ẹniti o mu Israeli ṣẹ̀, li ọjọ rẹ̀ gbogbo.
19 Fulu ọba Assiria si gbé ogun tì ilẹ na: Menahemu si fi ẹgbẹrin talenti fadakà fun Fulu, ki ọwọ rẹ̀ ki o le pẹlu on lati fi idi ijọba na mulẹ lọwọ rẹ̀.
20 Menahemu si fi agbara gbà owo na lọwọ Israeli, ani lọwọ gbogbo awọn ọlọrọ̀, ãdọta ṣekeli fadakà lọwọ olukuluku enia, lati fi fun ọba Assiria. Bẹ̃ni ọba Assiria yipada, kò si duro ni ilẹ na.
21 Ati iyokù iṣe Menahemu, ati gbogbo eyiti o ṣe, a kò ha kọ wọn sinu iwe ọ̀rọ ọjọ awọn ọba Israeli?
22 Menahemu si sùn pẹlu awọn baba rẹ̀; Pekahiah ọmọ rẹ̀ si jọba ni ipò rẹ̀.
23 Ni ãdọta ọdun Asariah ọba Juda, Pekahiah ọmọ Menahemu bẹ̀rẹ si ijọba lori Israeli ni Samaria, o si jọba ọdun meji.
24 O si ṣe eyiti o buru li oju Oluwa: on kò si lọ kuro ninu ẹ̀ṣẹ Jeroboamu ọmọ Nebati, ẹniti o mu Israeli ṣẹ̀.
25 Ṣugbọn Peka ọmọ Remaliah, olori-ogun rẹ̀, dì rikiṣi si i, o si kọlù u ni Samaria, li odi ile ọba, pẹlu Argobu, ati Arie, ati ãdọta enia ninu awọn ọmọ Gileadi pẹlu rẹ̀: o si pa a, o si jọba ni ipò rẹ̀.
26 Ati iyokù iṣe Pekahiah, ati gbogbo eyiti o ṣe, kiyesi i, a kọ wọn sinu iwe ọ̀rọ ọjọ awọn ọba Israeli.
27 Li ọdun kejilelãdọta Asariah ọba Juda ni Peka ọmọ Remaliah bẹ̀rẹ si ijọba lori Israeli ni Samaria, o si jọba li ogun ọdun.
28 O si ṣe eyiti o buru li oju Oluwa: on kò lọ kuro ninu ẹ̀ṣẹ Jeroboamu ọmọ Nebati, ẹniti o mu Israeli ṣẹ̀.
29 Li ọjọ Peka ọba Israeli ni Tiglat-pileseri ọba Assiria de, o si kó Ijoni, ati Abel-betmaaka, ati Janoa, ati Kedeṣi, ati Hasori, ati Gileadi, ati Galili, gbogbo ilẹ Naftali, o si kó wọn ni igbèkun lọ si Assiria.
30 Hoṣea ọmọ Ela si dì rikiṣi si Peka ọmọ Remaliah, o si kọlù u, o si pa a, o si jọba ni ipò rẹ̀, li ogun ọdun Jotamu ọmọ Ussiah.
31 Ati iyokù iṣe Peka, ati gbogbo eyiti o ṣe, kiyesi i, a kọ wọn sinu iwe ọ̀rọ ọjọ awọn ọba Israeli.
32 Li ọdun keji Peka ọmọ Remaliah ọba Israeli, ni Jotamu ọmọ Ussiah ọba Juda bẹ̀rẹ si ijọba.
33 Ẹni ọdun mẹ̃dọgbọ̀n ni, nigbati o bẹ̀rẹ si ijọba, o si jọba ọdun mẹrindilogun ni Jerusalemu. Orukọ iya rẹ̀ ni Jeruṣa, ọmọbinrin Sadoku.
34 O si ṣe eyiti o tọ́ li oju Oluwa: o si ṣe gẹgẹ bi gbogbo eyiti Ussiah baba rẹ̀ ti ṣe.
35 Ṣugbọn a kò mu ibi giga wọnni kuro: awọn enia nrubọ, nwọn si nsun turari sibẹ ni ibi giga wọnni. On kọ́ ẹnu-ọ̀na giga ile Oluwa.
36 Ati iyokù iṣe Jotamu, ati gbogbo eyiti o ṣe, a kò ha kọ wọn sinu iwe ọ̀rọ ọjọ awọn ọba Juda?
37 Li ọjọ wọnni Oluwa bẹ̀rẹ si irán Resini ọba Siria, ati Peka ọmọ Remaliah si Juda.
38 Jotamu si sùn pẹlu awọn baba rẹ̀, a si sin i pẹlu awọn baba rẹ̀ ni ilu Dafidi baba rẹ̀, Ahasi ọmọ rẹ̀ si jọba ni ipò rẹ̀.