1 OBIRIN kan ninu awọn obinrin ọmọ awọn woli ke ba Eliṣa wipe, Iranṣẹ rẹ, ọkọ mi kú; iwọ si mọ̀ pe iranṣẹ rẹ bẹ̀ru Oluwa: awọn onigbèse si wá lati mu awọn ọmọ mi mejeji li ẹrú.
2 Eliṣa si wi fun u pe, Kini emi o ṣe fun ọ? Wi fun mi, kini iwọ ni ninu ile? On si wipe, Iranṣẹbinrin rẹ kò ni nkankan ni ile, bikòṣe ikòko ororo kan.
3 On si wipe, Lọ, ki iwọ ki o yá ikòko lọwọ awọn aladugbò rẹ kakiri, ani ikòko ofo; yá wọn, kì iṣe diẹ.
4 Nigbati iwọ ba si wọle, ki iwọ ki o se ilẹ̀kun mọ ara rẹ, ati mọ awọn ọmọ rẹ, ki o si dà a sinu gbogbo ikòko wọnni, ki iwọ ki o si fi eyiti o kún si apakan.
5 O si lọ kuro lọdọ rẹ̀, o si se ilẹ̀kun mọ ara rẹ̀ ati mọ awọn ọmọ rẹ̀, ti ngbe ikòko fun u wá; on si dà a.
6 O si ṣe, nigbati awọn ikòko kún, o wi fun ọmọ rẹ̀ pe, Tun mu ikòko kan fun mi wá. On si wi fun u pe, Kò si ikòko kan mọ. Ororo na si da.
7 Nigbana li o wá, o si sọ fun enia Ọlọrun na. On si wipe, Lọ, tà ororo na, ki o si san gbèse rẹ, ki iwọ ati awọn ọmọ rẹ ki o si jẹ eyi ti o kù.
8 O si di ọjọ kan, Eliṣa si kọja si Ṣunemu, nibiti obinrin ọlọla kan wà; on si rọ̀ ọ lati jẹ onjẹ. O si ṣe, nigbakugba ti o ba nkọja lọ, on a yà si ibẹ lati jẹ onjẹ.
9 On si wi fun ọkọ rẹ̀ pe, Sa wò o na, emi woye pe, enia mimọ́ Ọlọrun li eyi ti ngbà ọdọ wa kọja nigbakugba.
10 Emi bẹ̀ ọ, jẹ ki a ṣe yàrá kekere kan lara ogiri; si jẹ ki a gbe ibùsùn kan sibẹ fun u, ati tabili kan, ati ohun-ijoko kan, ati ọpá-fitila kan: yio si ṣe, nigbati o ba tọ̀ wa wá, ki on ma wọ̀ sibẹ.
11 O si di ọjọ kan, ti o wá ibẹ̀, o si yà sinu yàrá na, o si dubulẹ nibẹ.
12 On si wi fun Gehasi iranṣẹ rẹ̀ pe, Pè ara Ṣunemu yi. Nigbati o si pè e, o duro niwaju rẹ̀.
13 On si wi fun u pe, nisisiyi, sọ fun u pe, Kiyesi i, iwọ ti fi gbogbo itọju yi ṣe aniyàn wa; kini a ba ṣe fun ọ? Iwọ nfẹ́ ki a sọ̀rọ rẹ fun ọba bi? tabi fun olori-ogun? On si dahùn wipe, Emi ngbe lãrin awọn enia mi.
14 On si wipe, Njẹ kini a ba ṣe fun u? Gehasi si dahùn pe, Nitõtọ, on kò li ọmọ, ọkọ rẹ̀ si di arugbo.
15 On si wipe, Pè e wá, nigbati o si ti pè e de, o duro li ẹnu-ọ̀na.
16 On si wipe, Li akokò yi gẹgẹ bi igba aiye, iwọ gbé ọmọkunrin kan mọra. On si wipe, Bẹ̃kọ̀, oluwa mi, iwọ enia Ọlọrun, má ṣe purọ fun iranṣẹbinrin rẹ.
17 Obinrin na si loyun, o si bi ọmọkunrin kan li akokò na ti Eliṣa ti sọ fun u, gẹgẹ bi igba aiye.
18 Nigbati ọmọ na si dagba, o di ọjọ kan, ti o jade tọ̀ baba rẹ̀ lọ si ọdọ awọn olukore.
19 O si wi fun baba rẹ̀ pe, Ori mi, ori mi! On si sọ fun ọmọ-ọdọ̀ kan pe, Gbé e tọ̀ iya rẹ̀ lọ.
20 Nigbati o si gbé e, ti o mu u tọ̀ iya rẹ̀ wá, o joko li ẽkun rẹ̀ titi di ọjọ kanri, o si kú.
21 On si gòke, o si tẹ́ ẹ sori ibùsun enia Ọlọrun na, o si sé ilẹ̀kun mọ ọ, o si jade lọ.
22 On si ke si ọkọ rẹ̀, o si wipe, Emi bẹ̀ ọ, rán ọkan ninu awọn ọdọmọkunrin si mi, ati ọkan ninu awọn kẹtẹkẹtẹ, emi o si sare tọ̀ enia Ọlọrun lọ, emi o si tun pada.
23 On si wipe, Ẽṣe ti iwọ o fi tọ̀ ọ lọ loni? kì isa ṣe oṣù titun, bẹ̃ni kì iṣe ọjọ isimi. On sì wipe, Alafia ni.
24 Nigbana li o di kẹtẹkẹtẹ ni gãri, o si wi fun iranṣẹ rẹ̀ pe, Mã le e, ki o si ma nṣo; máṣe dẹ̀ ire fun mi, bikòṣepe mo sọ fun ọ.
25 Bẹ̃li o lọ, o si de ọdọ enia Ọlọrun na li òke Karmeli. O si ṣe, nigbati enia Ọlọrun na ri i li okère, o si sọ fun Gehasi ọmọ ọdọ rẹ̀ pe, Wò ara Ṣunemu nì:
26 Emi bẹ̀ ọ, sure nisisiyi ki o pade rẹ̀, ki o si wi fun u pe, Alafia ki o wà bi? alafia ki ọkọ rẹ̀ wà bi? alafia ki ọmọde wà bi? On si dahùn wipe, Alafia ni.
27 Nigbati o si de ọdọ enia Ọlọrun li ori òke, o gbá a li ẹsẹ̀ mu: ṣugbọn Gehasi sunmọ ọ lati tì i kurò. Enia Ọlọrun na si wipe, Jọwọ rẹ̀ nitori ọkàn rẹ̀ bajẹ ninu rẹ̀, Oluwa si pa a mọ́ fun mi, kò si sọ fun mi.
28 Nigbana li o wipe, Mo ha tọrọ ọmọ li ọwọ oluwa mi bi? Emi kò ha wipe, Máṣe tàn mi jẹ?
29 O si wi fun Gehasi pe, Di àmure rẹ, ki o si mu ọpa mi li ọwọ rẹ, ki o si lọ, bi iwọ ba ri ẹnikẹni li ọ̀na, máṣe ki i; bi ẹnikeni ba si kí ọ, máṣe da a li ohùn: ki o si fi ọpá mi le iwaju ọmọ na.
30 Iya ọmọ na si wipe, Bi Oluwa ti mbẹ, ati bi ẹmi rẹ ti mbẹ, emi kì o fi ọ silẹ. On si dide, o si ntọ̀ ọ lẹhin.
31 Gehasi si kọja siwaju wọn, o si fi ọpá na le ọmọ na ni iwaju, ṣugbọn kò si ohùn, tabi afiyesi: nitorina o si tun pada lati lọ ipade rẹ̀, o si wi fun u pe, Ọmọ na kò ji.
32 Nigbati Eliṣa si wọ̀ inu ile, kiyesi i, ọmọ na ti kú, a si tẹ́ ẹ sori ibùsun rẹ̀.
33 O si wọ̀ inu ile lọ, o si se ilẹ̀kun mọ awọn mejeji, o si gbadura si Oluwa.
34 On si gòke, o si dubulẹ le ọmọ na, o si fi ẹnu rẹ̀ le ẹnu rẹ̀, ati oju rẹ̀ le oju rẹ̀, ati ọwọ rẹ̀ le ọwọ rẹ̀: on si nà ara rẹ̀ le ọmọ na, ara ọmọ na si di gbigboná.
35 O si pada, o si rìn lọ, rìn bọ̀ ninu ile lẹ̃kan; o si gòke, o si nà ara rẹ̀ le e; ọmọ na si sín nigba meje; ọmọ na si là oju rẹ̀.
36 O si pè Gehasi, o si wipe, Pè ara Ṣunemu yi wá. O si pè e. Nigbati o si wọle tọ̀ ọ wá, o ni, Gbé ọmọ rẹ.
37 Nigbana li o wọ̀ inu ile, o si wolẹ li ẹba ẹṣẹ̀ rẹ̀, o si dojubolẹ, o si gbé ọmọ rẹ̀, o si jade lọ.
38 Eliṣa si tun pada wá si Gilgali, iyàn si mu ni ilẹ na; awọn ọmọ awọn woli joko niwaju rẹ̀: on si wi fun iranṣẹ rẹ̀ pe, Gbe ìkoko nla ka iná, ki ẹ si pa ipẹ̀tẹ fun awọn ọmọ awọn woli.
39 Ẹnikan si jade lọ si igbẹ lati fẹ́ ewebẹ̀, o si ri ajara-igbẹ kan, o si ka eso rẹ̀ kún aṣọ rẹ̀, o si rẹ́ ẹ wẹwẹ, o dà wọn sinu ikoko ipẹ̀tẹ na: nitoripe nwọn kò mọ̀ wọn.
40 Bẹ̃ni nwọn si dà a fun awọn ọkunrin na lati jẹ. O si ṣe bi nwọn ti njẹ ipẹ̀tẹ na, nwọn si kigbe, nwọn si wipe, Iwọ enia Ọlọrun, ikú mbẹ ninu ikoko na! Nwọn kò si le jẹ ẹ.
41 Ṣugbọn on wipe, Njẹ, ẹ mu iyẹ̀fun wá. O si dà a sinu ikoko na, o si wipe, Dà a fun awọn enia, ki nwọn ki o le jẹ. Kò si si jamba ninu ikoko mọ.
42 Ọkunrin kan si ti Baali-Ṣaliṣa wá, o si mu àkara akọso-eso, ogun iṣu àkara barle, ati ṣiri ọkà titun ninu àpo rẹ̀ wá fun enia Ọlọrun na. On si wipe, Fi fun awọn enia, ki nwọn ki o le jẹ.
43 Iranṣẹ rẹ̀ si wipe, Kinla, ki emi ki o gbé eyi kà iwaju ọgọrun enia? On si tun wipe, Fi fun awọn enia, ki nwọn ki o le jẹ: nitori bayi li Oluwa wi pe, Nwọn o jẹ, nwọn o si kù silẹ.
44 Bẹ̃li o gbe e kà iwaju wọn, nwọn si jẹ, nwọn si kù silẹ, gẹgẹ bi ọ̀rọ Oluwa.