2. A. Ọba 20 YCE

Àìsàn Hesekaya Ọba, ati Ìwòsàn Rẹ̀

1 LI ọjọ wọnni ni Hesekiah ṣe aisàn de oju-ikú. Isaiah woli ọmọ Amosi si tọ̀ ọ wá, o si wi fun u pe, Bayi li Oluwa wi, Palẹ ile rẹ mọ́; nitoriti iwọ o kú, iwọ kì yio si yè.

2 Nigbana ni o yi oju rẹ̀ pada si ogiri, o si gbadura si Oluwa, wipe,

3 Emi bẹ̀ ọ, Oluwa, ranti nisisiyi bi emi ti rìn niwaju rẹ ninu otitọ ati ninu aiya pipe, ti mo si ti ṣe eyiti o dara li oju rẹ. Hesekiah si sọkún gidigidi.

4 O si ṣe, ki Isaiah ki o to jade si ãrin agbalá-ãfin, li ọ̀rọ Oluwa tọ̀ ọ wá wipe,

5 Tun pada, ki o si wi fun Hesekiah olori awọn enia mi pe, Bayi li Oluwa Ọlọrun Dafidi baba rẹ wi pe, Emi ti gbọ́ adura rẹ, emi si ti ri omije rẹ: kiyesi i, emi o wò ọ sàn: ni ijọ kẹta iwọ o gòke lọ si ile Oluwa.

6 Emi o si bù ọdun mẹ̃dogun kún ọjọ rẹ: emi o si gbà ọ ati ilu yi lọwọ ọba Assiria, emi o si dãbò bò ilu yi, nitori ti emi tikara mi, ati nitori ti Dafidi iranṣẹ mi.

7 Isaiah si wipe, Mu odidi ọ̀pọtọ. Nwọn si mu u, nwọn si fi le õwo na, ara rẹ̀ si da.

8 Hesekiah si wi fun Isaiah pe, Kini yio ṣe àmi pe Oluwa yio wò mi sàn, ati pe emi o gòke lọ si ile Oluwa ni ijọ kẹta?

9 Isaiah si wipe, Àmi yi ni iwọ o ni lati ọdọ Oluwa wá, pe, Oluwa yio ṣe nkan yi ti on ti sọ: ki ojiji ki o lọ siwaju ni iṣisẹ̀ mẹwa ni, tabi ki o pada sẹhin ni iṣisẹ̀ mẹwa?

10 Hesekiah si dahùn wipe, Ohun ti o rọrùn ni fun ojiji ki o lọ siwaju ni iṣisẹ̀ mẹwa: bẹ̃kọ, ṣugbọn jẹ ki ojiji ki o pada sẹhin ni iṣisẹ̀ mẹwa.

11 Isaiah woli si kepè Oluwa; on si mu ojiji pada sẹhin ni iṣisẹ̀ mẹwa, nipa eyiti o ti sọ̀kalẹ ninu agogo-õrùn Ahasi.

Àwọn Iranṣẹ láti Babilonii

12 Li akokò na ni Berodaki-Baladani, ọmọ Baladani, ọba Babeli, rán iwe ati ọrẹ si Hesekiah: nitoriti o ti gbọ́ pe Hesekiah ti ṣe aisàn.

13 Hesekiah si fi eti si ti wọn, o si fi gbogbo ile iṣura ohun iyebiye rẹ̀ hàn wọn, fadakà, ati wura, ati turari, ati ororo iyebiye, ati gbogbo ile ohun ihamọra rẹ̀, ati gbogbo eyiti a ri ninu iṣura rẹ̀: kò si nkan ni ile rẹ̀, tabi ni gbogbo ijọba rẹ̀, ti Hesekiah kò fi hàn wọn.

14 Nigbana ni Isaiah woli wá si ọdọ Hesekiah ọba, o si wi fun u pe, Kili awọn ọkunrin wọnyi wi? ati nibo ni nwọn ti wá si ọdọ rẹ? Hesekiah si wipe, Ilu òkere ni nwọn ti wá, ani lati Babeli:

15 On si wipe, Kini nwọn ri ni ile rẹ? Hesekiah si dahùn wipe, Gbogbo nkan ti mbẹ ni ile mi ni nwọn ti ri: kò si nkan ninu iṣura mi ti emi kò fi hàn wọn.

16 Isaiah si wi fun Hesekiah pe, Gbọ́ ọ̀rọ Oluwa.

17 Kiyesi i, ọjọ mbọ̀, ti a o kó gbogbo nkan ti mbẹ ninu ile rẹ, ati eyiti awọn baba rẹ ti tò jọ titi di oni, lọ si Babeli: ohun kan kì yio kù, li Oluwa wi.

18 Ati ninu awọn ọmọ rẹ ọkunrin ti yio ti inu rẹ jade wá, ti iwọ o bi, ni nwọn o kó lọ; nwọn o si mã ṣe iwẹ̀fa li ãfin ọba Babeli.

19 Nigbana ni Hesekiah wi fun Isaiah pe, Rere li ọ̀rọ Oluwa ti iwọ sọ. On si wipe, kò ha dara bi alafia ati otitọ ba wà lọjọ mi?

Ìgbẹ̀yìn Ìjọba Hesekaya

20 Ati iyokù iṣe Hesekiah ati gbogbo agbara rẹ̀, ati bi o ti ṣe adagun omi, ati ọ̀na omi na, ti o si mu omi wá sinu ilu, a kò ha kọ wọn sinu iwe ọ̀rọ ọjọ awọn ọba Juda?

21 Hesekiah si sùn pẹlu awọn baba rẹ̀: Manasse ọmọ rẹ̀ si jọba ni ipò rẹ̀.

orí

1 2 3 4 5 6 7 8 9 10 11 12 13 14 15 16 17 18 19 20 21 22 23 24 25