1 LI ọdun kẹtadilogun Peka ọmọ Remaliah, Ahasi ọmọ Jotamu ọba Juda bẹ̀rẹ si ijọba.
2 Ẹni ogún ọdun ni Ahasi nigbati o bẹ̀rẹ si ijọba, o si jọba ọdun mẹrindilogun ni Jerusalemu, kò si ṣe eyiti o tọ́ li oju Oluwa Ọlọrun rẹ̀, gẹgẹ bi Dafidi baba rẹ̀.
3 Ṣugbọn o rìn li ọ̀na awọn ọba Israeli, nitõtọ, o si mu ki ọmọ rẹ̀ ki o kọja lãrin iná pẹlu, gẹgẹ bi iṣe irira awọn keferi, ti Oluwa le jade niwaju awọn ọmọ Israeli.
4 O si rubọ, o si sun turari ni ibi giga wọnni, ati lori awọn òke kekeke, ati labẹ gbogbo igi tutu.
5 Nigbana ni Resini ọba Siria ati Peka ọmọ Remaliah ọba Israeli gòke wá si Jerusalemu lati jagun: nwọn si do tì Ahasi, ṣugbọn nwọn kò le bori rẹ̀.
6 Li akokò na, Resini ọba Siria gbà Elati pada fun Siria, o si lé awọn enia Juda kuro ni Elati: awọn ara Siria si wá si Elati, nwọn si ngbe ibẹ titi di oni yi.
7 Ahasi si rán onṣẹ si ọdọ Tiglat-pileseri ọba Assiria wipe, Iranṣẹ rẹ li emi, ati ọmọ rẹ; gòke wá, ki o si gbà mi lọwọ ọba Siria, ati lọwọ ọba Israeli, ti o dide si mi.
8 Ahasi si mu fadakà ati wura ti a ri ni ile Oluwa, ati ninu iṣura ile ọba, o si rán a li ọrẹ si ọba Assiria.
9 Ọba Assiria si gbọ́ tirẹ̀: nitoriti ọba Assiria gòke wá si Damasku, o si kó o, o si mu u ni igbèkun lọ si Kiri, o si pa Resini.
10 Ahasi ọba si lọ si Damasku lati pade Tiglat-pileseri, ọba Assiria, o si ri pẹpẹ kan ti o wà ni Damasku: Ahasi ọba si rán awòran pẹpẹ na, ati apẹrẹ rẹ̀ si Urijah alufa, gẹgẹ bi gbogbo iṣẹ ọnà rẹ̀.
11 Urijah alufa si ṣe pẹpẹ kan gẹgẹ bi gbogbo eyiti Ahasi ọba fi ranṣẹ si i lati Damasku wá; bẹ̃ni Urijah alufa ṣe e de atibọ̀ Ahasi ọba lati Damasku wá.
12 Nigbati ọba si ti Damasku de, ọba si ri pẹpẹ na: ọba si sunmọ pẹpẹ na, o si rubọ lori rẹ̀.
13 O si sun ẹbọ ọrẹ-sisun rẹ̀ ati ọrẹ-jijẹ rẹ̀, o si ta ohun-mimu rẹ̀ silẹ, o si wọ́n ẹ̀jẹ ọrẹ-alafia rẹ̀ si ara pẹpẹ na.
14 Ṣugbọn o mu pẹpẹ idẹ ti o wà niwaju Oluwa kuro lati iwaju ile na, lati agbedemeji pẹpẹ na, ati ile Oluwa, o si fi i si apa ariwa pẹpẹ na.
15 Ahasi ọba si paṣẹ fun Urijah alufa, wipe, Lori pẹpẹ nla ni ki o mã sun ọrẹ-sisun orowurọ̀ ati ọrẹ-jijẹ alalẹ, ati ẹbọ-sisun ti ọba, ati ọrẹ-jijẹ rẹ̀, pẹlu ọrẹ-sisun ti gbogbo awọn enia ilẹ na, ati ọrẹ-jijẹ wọn, ati ọrẹ ohun-mimu wọn; ki o si wọ́n gbogbo ẹ̀jẹ ọrẹ-sisun na lori rẹ̀, ati gbogbo ẹ̀jẹ ẹbọ miran: ṣugbọn niti pẹpẹ idẹ na emi o mã gbero ohun ti emi o fi i ṣe.
16 Bayi ni Urijah alufa ṣe, gẹgẹ bi gbogbo eyiti Ahasi ọba pa li aṣẹ.
17 Ahasi ọba si ké alafo ọnà arin awọn ijoko na, o si ṣi agbada na kuro lara wọn; o si gbé agbada-nla na kalẹ kuro lara awọn malu idẹ ti mbẹ labẹ rẹ̀, o si gbé e kà ilẹ ti a fi okuta tẹ́.
18 Ibi ãbò fun ọjọ isimi ti a kọ́ ninu ile na, ati ọ̀na ijade si ode ti ọba, ni o yipada kuro ni ile Oluwa nitori ọba Assiria.
19 Ati iyokù iṣe Ahasi ti o ṣe, a kò ha kọ wọn sinu iwe ọ̀rọ ọjọ awọn ọba Juda?
20 Ahasi si sùn pẹlu awọn baba rẹ̀, a si sin i pẹlu awọn baba rẹ̀ ni ilu Dafidi: Hesekiah ọmọ rẹ̀ si jọba ni ipò rẹ̀.