2. A. Ọba 18 YCE

Hesekaya, Ọba Juda

1 O si ṣe li ọdun kẹta Hoṣea ọmọ Ela ọba Israeli ni Hesekiah ọmọ Ahasi ọba Juda bẹ̀rẹ si ijọba.

2 Ẹni ọdun mẹ̃dọgbọ̀n li on nigbati o bẹ̀rẹ si ijọba; o si jọba li ọdun mọkandilọgbọ̀n ni Jerusalemu. Orukọ iya rẹ̀ ni Abi ọmọbinrin Sakariah.

3 O si ṣe eyiti o tọ́ li oju Oluwa, gẹgẹ bi gbogbo eyiti Dafidi baba rẹ̀ ti ṣe.

4 On mu ibi giga wọnni kuro, o si fọ́ awọn ere, o si wó awọn ere oriṣa lulẹ, o si fọ́ ejò idẹ na tútu ti Mose ti ṣe: nitori titi di ọjọ wọnni, awọn ọmọ Israeli nsun turari si i: a si pè e ni Nehuṣtani.

5 O gbẹkẹle Oluwa Ọlọrun Israeli; ati lẹhin rẹ̀ kò si ẹniti o dabi rẹ̀ ninu gbogbo awọn ọba Juda, bẹ̃ni ṣãju rẹ̀ kò si ẹnikan.

6 Nitoriti o faramọ Oluwa, kò si lọ kuro lẹhin rẹ̀, ṣugbọn o pa ofin rẹ̀ wọnni mọ, ti Oluwa ti pa li aṣẹ fun Mose.

7 Oluwa si wà pẹlu rẹ̀; o si ṣe rere nibikibi ti o ba jade lọ: o si ṣọ̀tẹ si ọba Assiria, kò si sìn i mọ.

8 On kọlù awọn ara Filistia, ani titi de Gasa, ati agbègbe rẹ̀, lati ile iṣọ awọn olùṣọ titi de ilu olodi.

9 O si ṣe li ọdun kẹrin Hesekiah ọba, ti iṣe ọdun keje Hoṣea ọmọ Ela ọba Israeli, ni Ṣalmaneseri ọba Assiria gòke wá si Samaria, o si dotì i.

10 Lẹhin ọdun mẹta nwọn kó o; ani li ọdun kẹfa Hesekiah, eyini ni ọdun kẹsan Hoṣea ọba Israeli li a kó Samaria.

11 Ọba Assiria si kó Israeli lọ si Assiria, o si fi wọn si Hala ati si Habori leti odò Gosani, ati si ilẹ awọn ara Media wọnni:

12 Nitoriti nwọn kò gbà ohùn Oluwa Ọlọrun wọn gbọ́, ṣugbọn nwọn dà majẹmu rẹ̀, ati ohun gbogbo ti Mose iranṣẹ Oluwa pa li aṣẹ, nwọn kò si fi eti si wọn, bẹ̃ni nwọn kò si ṣe wọn.

Asiria Halẹ̀ Mọ́ Jerusalẹmu

13 Li ọdun kẹrinla Hesekiah ọba, ni Sennakeribu ọba Assiria gòke wá si gbogbo awọn ilu olodi Juda, o si kó wọn.

14 Hesekiah ọba Juda si ranṣẹ si ọba Assiria ni Lakiṣi, wipe, Mo ti ṣẹ̀; padà lẹhin mi: eyiti iwọ ba bù fun mi li emi o rù. Ọba Assiria si bù ọ̃dunrun talenti fadakà, ati ọgbọ̀n talenti wura fun Hesekiah ọba Juda.

15 Hesekiah si fun u ni gbogbo fadakà ti a ri ni ile Oluwa, ati ninu iṣura ile ọba.

16 Li akòko na ni Hesekiah ké gbogbo wura kuro lara awọn ilẹ̀kun ile Oluwa, ati kuro lara ọwọ̀n wọnni ti Hesekiah ọba Juda ti fi wura bò, o si fi wọn fun ọba Assiria.

17 Ọba Assiria si rán Tartani, ati Rabsarisi, ati Rabṣake, lati Lakiṣi lọ si ọdọ Hesekiah ọba pẹlu ogun nla si Jerusalemu. Nwọn si gòke wá, nwọn si de Jerusalemu. Nwọn si gòke wá, nwọn de, nwọn si duro leti idari omi abàta òke, ti mbẹ li eti òpopo pápa afọṣọ.

18 Nigbati nwọn si ké si ọba, Eliakimu ọmọ Hilkiah ti iṣe olori ile na si jade tọ̀ wọn wá, ati Ṣebna akọwe, ati Joa ọmọ Asafu akọwe-iranti.

19 Rabṣake si wi fun wọn pe, Ẹ sọ fun Hesekiah nisisiyi pe, Bayi ni ọba nla, ọba Assiria wi pe, Kini igbẹkẹle yi ti iwọ gbẹkẹle?

20 Iwọ wipe (ṣugbọn ọ̀rọ ète lasan ni nwọn), emi ni ìmọ ati agbara lati jagun. Njẹ tani iwọ gbẹkẹle, ti iwọ fi ṣọ̀tẹ si mi?

21 Kiyesi i, nisisiyi, iwọ gbẹkẹle ọ̀pa iyè fifọ yi, ani le Egipti, lara ẹniti bi ẹnikan ba fi ara tì, yio wọ̀ ọ li ọwọ lọ, yio si gun u: bẹ̃ni Farao ọba Egipti ri fun gbogbo awọn ti o gbẹkẹ wọn le e.

22 Ṣugbọn bi ẹnyin ba wi fun mi pe, Awa gbẹkẹle Oluwa Ọlọrun wa: on ha kọ li ẹniti Hesekiah ti mu awọn ibi giga rẹ̀, ati awọn pẹpẹ rẹ̀ kuro, ti o si wi fun Juda ati Jerusalemu pe, Ẹnyin o ma sìn niwaju pẹpẹ yi ni Jerusalemu?

23 Njẹ nisisiyi, Mo bẹ̀ ọ, ba oluwa mi ọba Assiria ṣe adehun, emi o si fun ọ li ẹgbã ẹṣin, bi iwọ nipa tirẹ ba lè ni enia to lati gùn wọn.

24 Njẹ bawo ni iwọ o ha ti ṣe le yi oju balogun kan ti o kere jùlọ pada ninu awọn iranṣẹ oluwa mi, ti iwọ si gbẹkẹ rẹ le Egipti fun kẹkẹ́ ati fun ẹlẹṣin?

25 Emi ha dẹhin Oluwa gòke wá nisisiyi si ibi yi lati pa a run? Oluwa wi fun mi pe, Gòke lọ si ilẹ yi, ki o si pa a run.

26 Nigbana ni Eliakimu ọmọ Hilkiah, ati Ṣebna, ati Joa wi fun Rabṣake pe, Emi bẹ̀ ọ, ba awọn iranṣẹ rẹ sọ̀rọ li ède Siria; nitoriti awa gbọ́ ọ: ki o má si ṣe ba wa sọ̀rọ li ède Juda li leti awọn enia ti mbẹ lori odi.

27 Ṣugbọn Rabṣake sọ fun wọn pe, Oluwa mi ha rán mi si oluwa rẹ, ati si ọ, lati sọ ọ̀rọ wọnyi bi? kò ṣepe awọn ọkunrin ti o joko lori odi li o rán mi si, ki nwọn ki o le jẹ igbẹ́ ara wọn, ati ki nwọn ki o le mu ìtọ ara wọn pẹlu nyin?

28 Nigbana ni Rabṣake duro, o si kigbe li ohùn rara li ède Juda o si sọ wipe, Ẹ gbọ́ ọ̀rọ ọba nla, ọba Assiria:

29 Bayi li ọba wi pe, Ẹ máṣe jẹ ki Hesekiah tàn nyin jẹ: nitori kì yio le gbà nyin kuro lọwọ rẹ̀:

30 Ẹ máṣe jẹ ki Hesekiah mu nyin gbẹkẹle Oluwa, wipe, Ni gbigbà Oluwa yio gbà wa, a kì yio si fi ilu yi le ọba Assiria lọwọ.

31 Ẹ máṣe fi eti si ti Hesekiah: nitori bayi li ọba Assiria wi pe, Fi ẹbùn wá oju rere mi, ki ẹ si jade tọ̀ mi wá, ki olukuluku nyin ki o si mã jẹ ninu àjarà rẹ̀, ati olukuluku ninu igi ọ̀pọtọ rẹ̀, ki olukuluku nyin ki o si mu omi ninu àmu rẹ̀:

32 Titi emi o fi wá mu nyin kuro lọ si ilẹ bi ti ẹnyin tikara nyin, si ilẹ ọkà ati ọti-waini, ilẹ onjẹ ati ọgbà ajara, ilẹ ororo olifi ati ti oyin, ki ẹnyin ki o le yè, ki ẹ má ba kú: ki ẹ má si fi eti si ti Hesekiah, nigbati o ba ntàn nyin wipe, Oluwa yio gbà wa.

33 Ọkan ninu awọn oriṣa awọn orilẹ-ède ti igbà ilẹ rẹ̀ kuro lọwọ ọba Assiria ri bi?

34 Nibo li awọn oriṣa Hamati, ati Arpadi gbe wà? Nibo li awọn oriṣa Sefarfaimu, Hena, ati Ifa gbe wà? Nwọn ha gbà Samaria kuro lọwọ mi bi?

35 Tani ninu gbogbo awọn oriṣa ilẹ wọnni ti o gbà ilẹ wọn kuro lọwọ mi, ti Oluwa yio fi gbà Jerusalemu kuro lọwọ mi?

36 Ṣugbọn awọn enia pa ẹnu wọn mọ́, nwọn kò si da a li ohun ọ̀rọ kan: nitori aṣẹ ọba ni, pe, Ẹ máṣe da a li ohùn.

37 Nigbana ni Eliakimu ọmọ Hilkiah ti iṣe olori ile, ati Ṣebna akọwe, ati Joa ọmọ Asafu akọwe-iranti wá sọdọ Hesekiah, ti awọn, ti aṣọ wọn ni fifàya, nwọn si sọ ọ̀rọ Rabṣake fun u.

orí

1 2 3 4 5 6 7 8 9 10 11 12 13 14 15 16 17 18 19 20 21 22 23 24 25