2. A. Ọba 1:8-14 YCE

8 Nwọn si da a li ohùn pe, Ọkunrin Onirum li ara ni; o si dì àmure awọ mọ́ ẹgbẹ́ rẹ̀. On si wipe, Elijah ara Tiṣbi ni.

9 Nigbana ni ọba rán olori-ogun ãdọta kan pẹlu ãdọta rẹ̀. O si gòke tọ̀ ọ lọ: si kiyesi i, o joko lori òke kan. On si wi fun u pe, Iwọ enia Ọlọrun, ọba wipe, Sọ̀kalẹ.

10 Elijah si dahùn, o si wi fun olori-ogun ãdọta na pe, Bi emi ba ṣe enia Ọlọrun, jẹ ki iná ki o sọ̀kalẹ lati ọrun wá, ki o run ọ ati ãdọta rẹ. Iná si sọ̀kalẹ ti ọrun wá, o si run u ati ãdọta rẹ̀.

11 On si tun rán olori-ogun ãdọta miran pẹlu ãdọta rẹ̀. On si dahùn o si wi fun u pe, Iwọ enia Ọlọrun, Bayi li ọba wi, yara sọ̀kalẹ.

12 Elijah si dahùn, o si wi fun wọn pe, Bi emi ba ṣe enia Ọlọrun, jẹ ki iná ki o sọ̀kalẹ lati ọrun wá, ki o si run ọ ati ãdọta rẹ. Iná Ọlọrun si sọ̀kalẹ lati ọrun wá, o si run u ati ãdọta rẹ̀.

13 O si tun rán olori-ogun ãdọta ekẹta pẹlu ãdọta rẹ̀. Olori-ogun ãdọta kẹta si gòke, o si wá, o si wolẹ lori ẽkún rẹ̀ niwaju Elijah, o si bẹ̀ ẹ, o si wi fun u pe, Iwọ, enia Ọlọrun, emi bẹ̀ ọ́, jẹ ki ẹmi mi ati ẹmi awọn ãdọta ọmọ-ọdọ rẹ wọnyi, ki o ṣọwọn li oju rẹ.

14 Kiyesi i, iná sọ̀kalẹ lati ọrun wá, o si run olori-ogun meji arãdọta iṣãju pẹlu arãdọta wọn: njẹ nisisiyi, jẹ ki ẹmi mi ki o ṣọwọn li oju rẹ.