11 Awọn ẹ̀ṣọ si duro, olukulùku pẹlu ohun ijà rẹ̀ lọwọ rẹ̀ yi ọba ka, lati igun ọtún ile Oluwa, titi de igun osì ile Oluwa, nihà pẹpẹ ati ile Oluwa.
12 On si mu ọmọ ọba na jade wá o si fi ade de e lori, o si fun u ni iwe-ẹ̀ri; nwọn si fi i jọba, nwọn si fi ororo yàn a; nwọn si pàtẹwọ wọn, nwọn si wipe, Ki ọba ki o pẹ.
13 Nigbati Ataliah gbọ́ ariwo awọn ẹ̀ṣọ ati ti awọn enia, o tọ̀ awọn enia na wá ninu ile Oluwa.
14 Nigbati o si wò, kiyesi i, ọba duro ni ibuduro na, gẹgẹ bi iṣe wọn, ati awọn balogun, ati awọn afunpè duro lọdọ ọba; gbogbo enia ilẹ na si yọ̀, nwọn si fun ipè: Ataliah si fa aṣọ rẹ̀ ya, o si kigbe, pe, Ọtẹ̀! Ọtẹ̀!
15 Ṣugbọn Jehoiada alufa paṣẹ fun awọn olori ọ̀rọrún, ati awọn olori ogun, o si wi fun wọn pe, Ẹ mu u jade lati inu ile arin ẹgbẹ ogun: ẹniti o ba si tọ̀ ọ lẹhin ni ki ẹ fi idà pa. Nitoriti alufa na ti wipe, Ki a máṣe pa a ninu ile Oluwa.
16 Nwọn si gbé ọwọ le e; on si gbà ọ̀na ti awọn ẹṣin ngbà wọ̀ ile ọba: nibẹ ni a si pa a.
17 Jehoiada si da majẹmu lãrin Oluwa ati ọba ati awọn enia, pe, ki nwọn ki o mã ṣe enia Oluwa; ati lãrin ọba pẹlu awọn enia.