3 A si pa a mọ́ pẹlu rẹ̀ ni ile Oluwa li ọdun mẹfa. Ataliah si jọba lori ilẹ na.
4 Li ọdun keje Jehoiada si ranṣẹ o si mu awọn olori lori ọ̀rọrún, pẹlu awọn balogun, ati awọn olùṣọ, o si mu wọn wá si ọdọ rẹ̀ sinu ile Oluwa, o si ba wọn da majẹmu, o si mu wọn bura ni ile Oluwa, o si fi ọmọ ọba hàn wọn.
5 O si paṣẹ fun wọn wipe, Eyi ni nkan ti ẹnyin o ṣe; Idamẹta nyin ti nwọle li ọjọ isimi, yio ṣe olùtọju iṣọ ile ọba;
6 Idamẹta yio si wà li ẹnu ọ̀na Suri; idamẹta yio si wà li ẹnu-ọ̀na lẹhin ẹ̀ṣọ: bẹ̃li ẹnyin o tọju iṣọ́ ile na, lati da abo bò o.
7 Ati idajì gbogbo ẹnyin ti njade lọ li ọjọ isimi, ani awọn ni yio tọju iṣọ ile Oluwa yi ọba ka.
8 Ẹnyin o si pa agbo yi ọba ka, olukuluku pẹlu ohun ijà rẹ̀ li ọwọ rẹ̀: ẹniti o ba si wọ̀ arin ẹgbẹ́ ogun na, ki a pa a: ki ẹnyin ki o si wà pẹlu ọba bi o ti njade lọ, ati bi o ti mbọ̀wá ile.
9 Awọn olori ọrọrun ṣe gẹgẹ bi gbogbo eyiti Jehoiada alufa pa li aṣẹ: olukuluku wọn si mu awọn ọkunrin tirẹ̀ ti ibá wọle wá li ọjọ isimi, pẹlu awọn ti iba jade lọ li ọjọ isimi, nwọn si wá si ọdọ Jehoiada alufa.