9 Awọn olori ọrọrun ṣe gẹgẹ bi gbogbo eyiti Jehoiada alufa pa li aṣẹ: olukuluku wọn si mu awọn ọkunrin tirẹ̀ ti ibá wọle wá li ọjọ isimi, pẹlu awọn ti iba jade lọ li ọjọ isimi, nwọn si wá si ọdọ Jehoiada alufa.
10 Alufa na si fi ọ̀kọ ati asà Dafidi ọba ti o wà ni ile Oluwa fun awọn olori ọ̀rọrún.
11 Awọn ẹ̀ṣọ si duro, olukulùku pẹlu ohun ijà rẹ̀ lọwọ rẹ̀ yi ọba ka, lati igun ọtún ile Oluwa, titi de igun osì ile Oluwa, nihà pẹpẹ ati ile Oluwa.
12 On si mu ọmọ ọba na jade wá o si fi ade de e lori, o si fun u ni iwe-ẹ̀ri; nwọn si fi i jọba, nwọn si fi ororo yàn a; nwọn si pàtẹwọ wọn, nwọn si wipe, Ki ọba ki o pẹ.
13 Nigbati Ataliah gbọ́ ariwo awọn ẹ̀ṣọ ati ti awọn enia, o tọ̀ awọn enia na wá ninu ile Oluwa.
14 Nigbati o si wò, kiyesi i, ọba duro ni ibuduro na, gẹgẹ bi iṣe wọn, ati awọn balogun, ati awọn afunpè duro lọdọ ọba; gbogbo enia ilẹ na si yọ̀, nwọn si fun ipè: Ataliah si fa aṣọ rẹ̀ ya, o si kigbe, pe, Ọtẹ̀! Ọtẹ̀!
15 Ṣugbọn Jehoiada alufa paṣẹ fun awọn olori ọ̀rọrún, ati awọn olori ogun, o si wi fun wọn pe, Ẹ mu u jade lati inu ile arin ẹgbẹ ogun: ẹniti o ba si tọ̀ ọ lẹhin ni ki ẹ fi idà pa. Nitoriti alufa na ti wipe, Ki a máṣe pa a ninu ile Oluwa.