1 LI ọdun kẹtalelogun Joaṣi ọmọ Ahasiah ọba Juda, Jehoahasi ọmọ Jehu bẹ̀rẹ si ijọba lori Israeli ni Samaria.
2 On si ṣe eyiti o buru li oju Oluwa, o si tẹ̀le ẹ̀ṣẹ Jeroboamu ọmọ Nebati, ẹniti o mu Israeli ṣẹ̀: on kò si lọ kuro ninu rẹ̀.
3 Ibinu Oluwa si rú si Israeli, o si fi wọn le ọwọ Hasaeli ọba Siria, ati le ọwọ Benhadadi ọmọ Hasaeli, li ọjọ wọn gbogbo.
4 Jehoahasi si bẹ̀ Oluwa, Oluwa si gbọ́ tirẹ̀; nitoriti o ri inira Israeli, nitoriti ọba Siria ni wọn lara.
5 Oluwa si fun Israeli ni olugbala kan, bẹ̃ni nwọn si bọ́ lọwọ awọn ara Siria: awọn ọmọ Israeli si joko ninu agọ wọn bi ìgba atijọ.