1 LI ọdun kẹtalelogun Joaṣi ọmọ Ahasiah ọba Juda, Jehoahasi ọmọ Jehu bẹ̀rẹ si ijọba lori Israeli ni Samaria.
2 On si ṣe eyiti o buru li oju Oluwa, o si tẹ̀le ẹ̀ṣẹ Jeroboamu ọmọ Nebati, ẹniti o mu Israeli ṣẹ̀: on kò si lọ kuro ninu rẹ̀.
3 Ibinu Oluwa si rú si Israeli, o si fi wọn le ọwọ Hasaeli ọba Siria, ati le ọwọ Benhadadi ọmọ Hasaeli, li ọjọ wọn gbogbo.
4 Jehoahasi si bẹ̀ Oluwa, Oluwa si gbọ́ tirẹ̀; nitoriti o ri inira Israeli, nitoriti ọba Siria ni wọn lara.
5 Oluwa si fun Israeli ni olugbala kan, bẹ̃ni nwọn si bọ́ lọwọ awọn ara Siria: awọn ọmọ Israeli si joko ninu agọ wọn bi ìgba atijọ.
6 Ṣugbọn nwọn kò lọ kuro ninu ẹ̀ṣẹ ile Jeroboamu, ẹniti o mu Israeli ṣẹ̀, ṣugbọn nwọn rìn ninu rẹ̀: ere-oriṣa si wà ni Samaria pẹlu.
7 Bẹ̃ni kò kù ninu awọn enia fun Jehoahasi, bikòṣe ãdọta ẹlẹṣin, ati kẹkẹ́ mẹwa, ati ẹgbãrin ẹlẹsẹ̀; nitoriti ọba Siria ti pa wọn run, o si ti lọ̀ wọn mọlẹ bi ẽkuru.