22 Ṣugbọn Hasaeli ọba Siria ni Israeli lara ni gbogbo ọjọ Jehoahasi.
23 Oluwa si ṣe oju rere si wọn, o si ṣãnu fun wọn, o si ṣe akiyesi wọn, nitoriti majẹmu rẹ̀ pẹlu Abrahamu, Isaaki, ati Jakobu, kò si fẹ run wọn, bẹ̃ni kò si ta wọn nù kuro niwaju rẹ̀ titi di isisiyi.
24 Bẹ̃ni Hasaeli ọba Siria kú; Benhadadi ọmọ rẹ̀ si jọba ni ipò rẹ̀.
25 Jehoaṣi ọmọ Jehoahasi si tun gbà ilu wọnni pada lọwọ Benhadadi ọmọ Hasaeli, ti o ti fi ogun gbà lọwọ Jehoahasi baba rẹ̀. Igba mẹta ni Joaṣi ṣẹgun rẹ̀, o si gbà awọn ilu Israeli pada.