5 Oluwa si fun Israeli ni olugbala kan, bẹ̃ni nwọn si bọ́ lọwọ awọn ara Siria: awọn ọmọ Israeli si joko ninu agọ wọn bi ìgba atijọ.
6 Ṣugbọn nwọn kò lọ kuro ninu ẹ̀ṣẹ ile Jeroboamu, ẹniti o mu Israeli ṣẹ̀, ṣugbọn nwọn rìn ninu rẹ̀: ere-oriṣa si wà ni Samaria pẹlu.
7 Bẹ̃ni kò kù ninu awọn enia fun Jehoahasi, bikòṣe ãdọta ẹlẹṣin, ati kẹkẹ́ mẹwa, ati ẹgbãrin ẹlẹsẹ̀; nitoriti ọba Siria ti pa wọn run, o si ti lọ̀ wọn mọlẹ bi ẽkuru.
8 Ati iyokù iṣe Jehoahasi, ati gbogbo eyiti o ṣe, ati agbara rẹ̀, a kò ha kọ wọn sinu iwe ọ̀rọ ọjọ awọn ọba Israeli.
9 Jehoahasi si sùn pẹlu awọn baba rẹ̀; nwọn si sìn i ni Samaria: Joaṣi ọmọ rẹ̀ si jọba ni ipò rẹ̀.
10 Li ọdun kẹtadilogoji Joaṣi ọba Juda, Jehoaṣi ọmọ Jehoahasi bẹ̀rẹ si ijọba lori Israeli ni Samaria, o si jọba li ọdun mẹrindilogun.
11 On si ṣe eyiti o buru li oju Oluwa; on kò lọ kuro ninu gbogbo ẹ̀ṣẹ Jeroboamu ọmọ Nebati, ẹniti o mu Israeli ṣẹ̀: ṣugbọn o rìn ninu wọn.