13 Jehoaṣi ọba Israeli si mu Amasiah ọba Juda, ọmọ Jehoaṣi ọmọ Ahasiah ni Betṣemeṣi, o si wá si Jerusalemu, o si wó odi Jerusalemu palẹ lati ẹnu bodè Efraimu titi de ẹnu bodè igun, irinwo igbọnwọ.
14 O si kó gbogbo wura ati fadakà, ati gbogbo ohun èlo ti a ri ninu ile Oluwa, ati ninu iṣura ile ọba, ati ògo, o si pada si Samaria.
15 Ati iyokù iṣe Jehoaṣi ti o ṣe, ati agbara rẹ̀, ati bi o ti ba Amasiah ọba Judah jà, a kò ha kọ wọn sinu iwe ọ̀rọ ọjọ awọn ọba Israeli?
16 Jehoaṣi si sùn pẹlu awọn baba rẹ̀, a si sin i ni Samaria pẹlu awọn ọba Israeli; Jeroboamu ọmọ rẹ̀ si jọba ni ipò rẹ̀.
17 Amasiah ọmọ Joaṣi ọba Juda wà li ọdun mẹ̃dogun lẹhin ikú Jehoaṣi ọmọ Jehoahasi ọba Israeli.
18 Ati iyokù iṣe Amasiah, a kò ha kọ wọn sinu iwe ọ̀rọ ọjọ awọn ọba Juda?
19 Nwọn si dì rikiṣi si i ni Jerusalemu: o si salọ si Lakiṣi; ṣugbọn nwọn ranṣẹ tọ̀ ọ ni Lakiṣi, nwọn si pa a nibẹ.