20 Iwọ wipe (ṣugbọn ọ̀rọ ète lasan ni nwọn), emi ni ìmọ ati agbara lati jagun. Njẹ tani iwọ gbẹkẹle, ti iwọ fi ṣọ̀tẹ si mi?
21 Kiyesi i, nisisiyi, iwọ gbẹkẹle ọ̀pa iyè fifọ yi, ani le Egipti, lara ẹniti bi ẹnikan ba fi ara tì, yio wọ̀ ọ li ọwọ lọ, yio si gun u: bẹ̃ni Farao ọba Egipti ri fun gbogbo awọn ti o gbẹkẹ wọn le e.
22 Ṣugbọn bi ẹnyin ba wi fun mi pe, Awa gbẹkẹle Oluwa Ọlọrun wa: on ha kọ li ẹniti Hesekiah ti mu awọn ibi giga rẹ̀, ati awọn pẹpẹ rẹ̀ kuro, ti o si wi fun Juda ati Jerusalemu pe, Ẹnyin o ma sìn niwaju pẹpẹ yi ni Jerusalemu?
23 Njẹ nisisiyi, Mo bẹ̀ ọ, ba oluwa mi ọba Assiria ṣe adehun, emi o si fun ọ li ẹgbã ẹṣin, bi iwọ nipa tirẹ ba lè ni enia to lati gùn wọn.
24 Njẹ bawo ni iwọ o ha ti ṣe le yi oju balogun kan ti o kere jùlọ pada ninu awọn iranṣẹ oluwa mi, ti iwọ si gbẹkẹ rẹ le Egipti fun kẹkẹ́ ati fun ẹlẹṣin?
25 Emi ha dẹhin Oluwa gòke wá nisisiyi si ibi yi lati pa a run? Oluwa wi fun mi pe, Gòke lọ si ilẹ yi, ki o si pa a run.
26 Nigbana ni Eliakimu ọmọ Hilkiah, ati Ṣebna, ati Joa wi fun Rabṣake pe, Emi bẹ̀ ọ, ba awọn iranṣẹ rẹ sọ̀rọ li ède Siria; nitoriti awa gbọ́ ọ: ki o má si ṣe ba wa sọ̀rọ li ède Juda li leti awọn enia ti mbẹ lori odi.