1 LI ọjọ rẹ̀ ni Nebukadnessari ọba Babeli gòke wá, Jehoiakimu si di iranṣẹ rẹ̀ li ọdun mẹta: nigbana li o pada o si ṣọ̀tẹ si i.
2 Oluwa si rán ẹgbẹ́ ogun awọn ara Kaldea si i, ati ẹgbẹ́ ogun awọn ara Siria, ati ẹgbẹ́ ogun awọn ara Moabu, ati ẹgbẹ́ ogun awọn ọmọ Ammoni, o si rán wọn si Juda lati pa a run, gẹgẹ bi ọ̀rọ Oluwa, ti o ti sọ nipa awọn iranṣẹ rẹ̀ awọn woli.
3 Nitõtọ lati ẹnu Oluwa li eyi ti wá sori Juda, lati mu wọn kuro niwaju rẹ̀, nitori ẹ̀ṣẹ Manasse, gẹgẹ bi gbogbo eyiti o ṣe;
4 Ati nitori ẹ̀jẹ alaiṣẹ̀ ti o ta silẹ pẹlu: nitoriti o fi ẹ̀jẹ alaiṣẹ̀ kún Jerusalemu; ti Oluwa kò fẹ darijì.