1 O si ṣe li ọdun kẹsan ijọba rẹ̀, li oṣù kẹwa, li ọjọ kẹwa oṣù, ni Nebukadnessari ọba Babeli de, on, ati gbogbo ogun rẹ̀, si Jerusalemu, o si dotì i; nwọn si mọdi tì i yika kiri.
2 A si dotì ilu na titi di ọdun ikọkanla Sedekiah.
3 Ati li ọjọ kẹsan oṣù kẹrin, iyàn mu gidigidi ni ilu, kò si si onjẹ fun awọn enia ilẹ na.
4 Ilu na si fọ́, gbogbo awọn ọkunrin ologun si gbà ọ̀na bodè lãrin odi meji, ti o wà leti ọgbà ọba, salọ li oru; (awọn ara Kaldea si yi ilu na kakiri;) ọba si ba ọ̀na pẹ̀tẹlẹ lọ.