4 Ilu na si fọ́, gbogbo awọn ọkunrin ologun si gbà ọ̀na bodè lãrin odi meji, ti o wà leti ọgbà ọba, salọ li oru; (awọn ara Kaldea si yi ilu na kakiri;) ọba si ba ọ̀na pẹ̀tẹlẹ lọ.
5 Ogun awọn ara Kaldea si lepa ọba, nwọn si ba a ni pẹ̀tẹlẹ Jeriko: gbogbo ogun rẹ̀ si tuka kuro lọdọ rẹ̀.
6 Bẹ̃ni nwọn mu ọba, nwọn si mu u gòke lọ si ọdọ ọba Babeli ni Ribla; nwọn si sọ ọ̀rọ idajọ lori rẹ̀.
7 Nwọn si pa awọn ọmọ Sedekiah li oju rẹ̀, nwọn si fọ Sedekiah li oju, nwọn si fi ẹwọn idẹ dè e, nwọn si mu u lọ si Babeli.
8 Ati li oṣù karun, li ọjọ keje oṣù, ti iṣe ọdun ikọkandilogun Nebukadnessari ọba, ọba Babeli, ni Nebusaradani olori ẹ̀ṣọ, iranṣẹ ọba Babeli, wá si Jerusalemu:
9 O si fi ile Oluwa joná, ati ile ọba, ati gbogbo ile Jerusalemu, ati gbogbo ile enia nla li o fi iná sun.
10 Gbogbo ogun awọn ara Kaldea ti o wà lọdọ olori ẹ̀ṣọ, si wó odi Jerusalemu palẹ yika kiri.