4 Meṣa, ọba Moabu si nsìn agutan, o si nsan ọkẹ marun ọdọ-agutan, ati ọkẹ marun àgbo irun fun ọba Israeli.
5 O si ṣe, nigbati Ahabu kú, ọba Moabu si ṣọ̀tẹ si ọba Israeli.
6 Jehoramu ọba si jade lọ kuro ni Samaria li akoko na, o si ka iye gbogbo Israeli.
7 O si lọ, o ranṣẹ si Jehoṣafati ọba Juda, wipe, Ọba Moabu ti ṣọ̀tẹ si mi: iwọ o ha bá mi lọ si Moabu lati jagun? On si wipe, Emi o gòke lọ: emi bi iwọ, enia mi bi enia rẹ, ati ẹṣin mi bi ẹṣin rẹ.
8 On si wipe, Ọ̀na wo li awa o gbà gòke lọ? On si dahùn wipe, Ọ̀na aginju Edomu.
9 Bẹ̃ni ọba Israeli lọ, ati ọba Juda, ati ọba Edomu: nigbati nwọn rìn àrinyika ijọ meje, omi kò si si nibẹ fun awọn ogun, ati fun ẹranko ti ntọ̀ wọn lẹhin.
10 Ọba Israeli si wipe, O ṣe! ti Oluwa fi pè awọn ọba mẹtẹta wọnyi jọ, lati fi wọn le Moabu lọwọ!