1 OBIRIN kan ninu awọn obinrin ọmọ awọn woli ke ba Eliṣa wipe, Iranṣẹ rẹ, ọkọ mi kú; iwọ si mọ̀ pe iranṣẹ rẹ bẹ̀ru Oluwa: awọn onigbèse si wá lati mu awọn ọmọ mi mejeji li ẹrú.
2 Eliṣa si wi fun u pe, Kini emi o ṣe fun ọ? Wi fun mi, kini iwọ ni ninu ile? On si wipe, Iranṣẹbinrin rẹ kò ni nkankan ni ile, bikòṣe ikòko ororo kan.
3 On si wipe, Lọ, ki iwọ ki o yá ikòko lọwọ awọn aladugbò rẹ kakiri, ani ikòko ofo; yá wọn, kì iṣe diẹ.
4 Nigbati iwọ ba si wọle, ki iwọ ki o se ilẹ̀kun mọ ara rẹ, ati mọ awọn ọmọ rẹ, ki o si dà a sinu gbogbo ikòko wọnni, ki iwọ ki o si fi eyiti o kún si apakan.
5 O si lọ kuro lọdọ rẹ̀, o si se ilẹ̀kun mọ ara rẹ̀ ati mọ awọn ọmọ rẹ̀, ti ngbe ikòko fun u wá; on si dà a.