21 Ọba Israeli si wi fun Eliṣa, nigbati o ri wọn pe, Baba mi, ki emi ki o mã pa wọn bi? ki emi ki o mã pa wọn bi?
22 On si dahùn pe, Iwọ kò gbọdọ pa wọn: iwọ jẹ pa awọn ti iwọ fi idà rẹ ati ọrun rẹ kó ni igbèkun? Gbe onjẹ ati omi kalẹ niwaju wọn, ki nwọn ki o jẹ, ki nwọn ki o si mu, ki nwọn ki o si tọ̀ oluwa wọn lọ.
23 On si pèse ọ̀pọlọpọ onjẹ fun wọn; nigbati nwọn si ti jẹ, ti nwọn si ti mu tan, o rán wọn lọ, nwọn si tọ̀ oluwa wọn lọ. Bẹ̃ni ẹgbẹ́ ogun Siria kò tun wá si ilẹ Israeli mọ.
24 O si ṣe lẹhìn eyi, ni Benhadadi ọba Siria ko gbogbo ogun rẹ̀ jọ, nwọn si gòke, nwọn si dó tì Samaria.
25 Iyàn nla kan si mu ni Samaria: si kiyesi i, nwọn dó tì i, tobẹ̃ ti a si fi ntà ori kẹtẹkẹtẹ kan ni ọgọrun iwọ̀n fadakà, ati idamẹrin oṣuwọn kabu imi ẹiyẹle, ni iwọ̀n fàdakà marun.
26 O si ṣe ti ọba Israeli nkọja lọ lori odi, obinrin kan sọkún tọ̀ ọ wá wipe, Gbà mi, oluwa mi, ọba!
27 On si wipe, Bi Oluwa kò ba gbà ọ, nibo li emi o gbe ti gbà ọ? Lati inu ilẹ-ipakà, tabi lati inu ibi ifunti?