2. A. Ọba 7:11-17 YCE

11 Ẹnikan si pè awọn onibodè; nwọn si sọ ninu ile ọba.

12 Ọba si dide li oru, o si wi fun awọn iranṣẹ rẹ̀ pe, Emi o fi hàn nyin nisisiyi eyiti awọn ara Siria ti ṣe si wa. Nwọn mọ̀ pe, ebi npa wa; nitorina nwọn jade lọ ni bùdo lati fi ara wọn pamọ́ ni igbẹ wipe, Nigbati nwọn ba jade ni ilu, awa o mu wọn lãyè, awa o si wọ̀ inu ilu lọ.

13 Ọkan ninu awọn iranṣẹ rẹ̀ si dahùn o si wipe, Emi bẹ̀ ọ, jẹ ki awa ki o mu marun ninu ẹṣin ti o kù, ninu awọn ti o kù ni ilu, kiyesi i, nwọn sa dabi gbogbo ọ̀pọlọpọ Israeli ti o kù ninu rẹ̀; kiyesi i, ani bi gbogbo ọ̀pọlọpọ enia Israeli ti a run, si jẹ ki a ranṣẹ lọ iwò.

14 Nitorina nwọn mu ẹṣin kẹkẹ́ meji; ọba si ranṣẹ tọ̀ ogun awọn ara Siria lẹhin, wipe, Ẹ lọ iwò.

15 Nwọn si tọ̀ wọn lẹhin de Jordani: si wò o, gbogbo ọ̀na kún fun agbáda ati ohun elò ti awọn ara Siria gbé sọnù ni iyára wọn. Awọn onṣẹ si pada, nwọn si sọ fun ọba.

16 Awọn enia si jade lọ, nwọn si kó ibùdo awọn ara Siria. Bẹ̃ni a ntà oṣùwọn iyẹ̀fun kikunná kan ni ṣekeli kan, ati oṣuwọn barle meji ni ṣekeli kan, gẹgẹ bi ọ̀rọ Oluwa.

17 Ọba si yàn ijòye na, lọwọ ẹniti o nfi ara tì, lati ṣe itọju ẹnu bodè: awọn enia si tẹ̀ ẹ mọlẹ ni bodè, o si kú, bi enia Ọlọrun na ti wi, ẹniti o sọ̀rọ nigbati ọba sọ̀kalẹ tọ̀ ọ wá.