2. A. Ọba 7:2-8 YCE

2 Nigbana ni ijòye kan li ọwọ ẹniti ọba nfi ara tì dá enia Ọlọrun li ohùn, o si wipe, Kiyesi i, bi Oluwa tilẹ sé ferese li ọrun, nkan yi ha le ri bẹ̃? On si wipe, Kiyesi i, iwọ o fi oju rẹ ri i, ṣugbọn iwọ kì yio jẹ ninu rẹ̀.

3 Adẹtẹ̀ mẹrin kan si wà ni atiwọ̀ bodè; nwọn si wi fun ara wọn pe, Ẽṣe ti awa fi joko nihinyi titi awa o fi kú?

4 Bi awa ba wipe, Awa o wọ̀ ilu lọ, iyàn si mbẹ ni ilu, awa o si kú nibẹ: bi awa ba si joko jẹ nihinyi, awa o kú pẹlu. Njẹ nisisiyi ẹ wá, ẹ jẹ ki awa ki o ṣubu si ọwọ ogun awọn ara Siria: bi nwọn ba dá wa si, awa o yè: bi nwọn ba si pa wa, awa o kú na ni.

5 Nwọn si dide li afẹ̀mọjumọ lati lọ si ibùdo awọn ara Siria: nigbati nwọn si de apa ti o kangun ibùdo Siria, kiyesi i, kò si ọkunrin kan nibẹ.

6 Nitori ti Oluwa ṣe ki ogun awọn ara Siria ki o gbọ́ ariwo kẹkẹ́, ati ariwo ẹṣin, ariwo ogun nla: nwọn si wi fun ara wọn pe, Kiyesi i, ọba Israeli ti bẹ̀ ogun awọn ọba Hitti, ati awọn ọba Egipti si wa, lati wá bò wa mọlẹ.

7 Nitorina ni nwọn dide, nwọn si salọ ni afẹ̀mọjumọ, nwọn si fi agọ wọn silẹ, ati ẹṣin wọn, ati kẹtẹkẹtẹ wọn, ani, ibùdo wọn gẹgẹ bi o ti wà, nwọn si salọ fun ẹmi wọn.

8 Nigbati adẹtẹ̀ wọnyi de apa ikangun bùdo, nwọn wọ inu agọ kan lọ, nwọn jẹ, nwọn si mu, nwọn sì kó fadakà ati wura ati agbáda lati ibẹ lọ, nwọn si lọ, nwọn si pa a mọ́; nwọn si tún pada wá, nwọn si wọ̀ inu agọ miran lọ, nwọn si kó lati ibẹ lọ pẹlu, nwọn si lọ, nwọn si pa a mọ́.