1 ELIṢA si wi fun obinrin na, ọmọ ẹniti o ti sọ di ãyè, wipe, Dide, si lọ, iwọ ati ile rẹ, ki o si ṣe atipo nibikibi ti iwọ ba le ṣe atipo: nitoriti Oluwa pe ìyan: yio si mu pẹlu ni ilẹ, li ọdun meje.
2 Obinrin na si dide, o si ṣe gẹgẹ bi ọ̀rọ enia Ọlọrun na: on si lọ pẹlu ile rẹ̀, nwọn si ṣe atipo ni ilẹ awọn ara Filistia li ọdun meje.
3 O si ṣe lẹhin ọdun meje, ni obinrin na pada bọ̀ lati ilẹ awọn ara Filistia: on si jade lọ lati kepè ọba nitori ile rẹ̀ ati nitori ilẹ rẹ̀.
4 Ọba si mba Gehasi iranṣẹ enia Ọlọrun na sọ̀rọ, wipe, Mo bẹ̀ ọ, sọ gbogbo ohun nla, ti Eliṣa ti ṣe fun mi.