1 ELIṢA woli si pè ọkan ninu awọn ọmọ woli, o si wi fun u pe, Dì amurè ẹ̀gbẹ rẹ, ki o si mu igò ororo yi lọwọ rẹ, ki o si lọ si Ramoti-Gileadi:
2 Nigbati iwọ ba si de ibẹ, ki iwọ ki o wá Jehu ọmọ Jehoṣafati, ọmọ Nimṣi li awari nibẹ, ki o si wọle, ki o si mu u ki o dide kuro lãrin awọn arakunrin rẹ̀, ki o si mu u lọ si yàra inu ile lọhun;
3 Ki o si mu igò ororo na, ki o si tú u si ori rẹ̀, ki o si wipe, Bayi li Oluwa wipe, Emi fi ororo yàn ọ li ọba li ori Israeli. Si ṣi ilẹkun, ki o si sá, má si ṣe duro.
4 Bẹ̃ni ọdọmọkunrin na, ani ọdọmọkunrin woli na, lọ si Ramoti-Gileadi.
5 Nigbati o si debẹ, kiyesi i, awọn olori-ogun wà ni ijoko; on si wipe, Emi ni iṣẹ kan si ọ, balogun. Jehu si wipe, Si tani ninu gbogbo wa? On si wipe, Si ọ, balogun.