6 Ati ọba ati awọn ọmọkunrin rẹ̀ si lọ Jerusalemu sọdọ awọn ara Jebusi, awọn enia ilẹ na: awọn ti o si ti wi fun Dafidi pe, Bikoṣepe iwọ ba mu awọn afọju ati awọn arọ kuro, iwọ ki yio wọ ìhin wá: nwọn si wipe, Dafidi ki yio lè wá sihin.
7 Ṣugbọn Dafidi si fi agbara gbà ilu odi Sioni: eyi na ni iṣe ilu Dafidi.
8 Dafidi si sọ lọjọ na pe, Ẹnikẹni ti yio kọlu awọn ara Jebusi, jẹ ki o gbà oju àgbàrá, ki o si kọlu awọn arọ ati awọn afọju ti ọkàn Dafidi korira. Nitorina ni nwọn ṣe wipe, Afọju ati arọ wà nibẹ, kì yio le wọle.
9 Dafidi si joko ni ile awọn ọmọ-ogun ti o ni odi, a si npè e ni ilu Dafidi. Dafidi mọ ògiri yi i ka lati Millo wá, o si kọ ile ninu rẹ̀.
10 Dafidi si npọ̀ si i, Oluwa Ọlọrun awọn ọmọ-ogun si wà pẹlu rẹ̀.
11 Hiramu ọba Tire si rán awọn iranṣẹ si Dafidi, ati igi kedari, ati awọn gbẹnàgbẹnà, ati awọn ti ngbẹ́ okuta ogiri: nwọn si kọ́ ile kan fun Dafidi.
12 Dafidi si kiyesi i pe, Oluwa ti fi idi on mulẹ lati jọba lori Israeli, ati pe, o gbe ijọba rẹ̀ ga nitori Israeli awọn enia rẹ̀.