1 Ọ̀RỌ Nehemiah ọmọ Hakaliah. O si ṣe ninu oṣu Kisleu, ni ogún ọdun, nigba tí mo wà ni Ṣuṣani ãfin.
2 Ni Hanani, ọkan ninu awọn arakunrin mi, on ati awọn ọkunrin kan lati Juda wá sọdọ mi; mo si bi wọn lere niti awọn ara Juda ti o salà, ti o kù ninu awọn igbekùn, ati niti Jerusalemu.
3 Nwọn si wi fun mi pe, Awọn iyokù, ti a fi silẹ nibẹ ninu awọn igbekùn ni igberiko, mbẹ ninu wahala nla ati ẹ̀gan; odi Jerusalemu si wó lulẹ̀, a si fi ilẹkùn rẹ̀ joná.
4 O si ṣe nigbati mo gbọ́ ọ̀rọ wọnyi, mo joko, mo si sọkun, mo si ṣọ̀fọ ni iye ọjọ, mo si gbãwẹ, mo si gbàdura niwaju Ọlọrun ọrun.
5 Mo si wipe, Emi mbẹ̀bẹ lọdọ rẹ, Oluwa Ọlọrun ọrun, ti o tobi, ti o si li ẹ̀ru, ti npa majẹmu ati ãnu mọ fun awọn ti o fẹ ẹ, ti nwọn si pa ofin rẹ̀ mọ: