1 NIGBANA ni gbogbo awọn enia ko ara wọn jọ bi enia kan si ita ti o wà niwaju ẹnu-bode omi; nwọn si sọ fun Esra akọwe lati mu iwe ofin Mose wá, ti Oluwa ti paṣẹ fun Israeli.
2 Esra alufa si mu ofin na wá iwaju ijọ t'ọkunrin t'obinrin, ati gbogbo awọn ti o le fi oye gbọ́, li ọjọ kini oṣu ekeje.
3 O si kà ninu rẹ̀ niwaju ita ti o wà niwaju ẹnu-bode omi lati owurọ titi di idaji ọjọ, niwaju awọn ọkunrin ati awọn obinrin, ati awọn ti o le ye; gbogbo enia si tẹtisilẹ si iwe ofin.
4 Esra akọwe si duro lori aga iduro sọ̀rọ, ti nwọn ṣe nitori eyi na: lẹba ọdọ rẹ̀ ni Mattitiah si duro, ati Ṣema, ati Anaiah, ati Urijah, ati Hilkiah, ati Maaseiah, li ọwọ ọtun rẹ̀; ati li ọwọ òsi rẹ̀ ni Pedaiah, ati Miṣaeli, ati Malkiah, ati Haṣumu, ati Haṣbadana, Sekariah, ati Meṣullamu.
5 Esra si ṣi iwe na li oju gbogbo enia; (nitori on ga jù gbogbo enia) nigbati o si ṣi i, gbogbo enia dide duro:
6 Esra si fi ibukun fun Oluwa Ọlọrun, ti o tobi. Gbogbo enia si dahun pe, Amin, Amin! pẹlu gbigbe ọwọ wọn soke: nwọn si tẹ̀ ori wọn ba, nwọn si sìn Oluwa ni idojubòlẹ̀.
7 Jeṣua pẹlu ati Bani, ati Ṣerebiah, Jamini, Akkubu, Ṣabbetai, Hodijah, Maaseiah, Kelita, Asariah, Josabadi, Hanani, Pelaiah, ati awọn ọmọ Lefi, mu ki ofin ye awọn enia: awọn enia si duro ni ipò wọn.
8 Bẹ̃ni nwọn kà ninu iwe ofin Ọlọrun ketekete, nwọn tumọ rẹ̀, nwọn si mu ki iwe kikà na ye wọn.
9 Ati Nehemiah ti iṣe bãlẹ, ati Esra alufa, akọwe, ati awọn ọmọ Lefi, ti o kọ́ awọn enia wi fun gbogbo enia pe, Ọjọ yi jẹ mimọ́ fun Oluwa Ọlọrun nyin; ẹ má ṣọ̀fọ ki ẹ má si sọkún. Nitori gbogbo awọn enia sọkún, nigbati nwọn gbọ́ ọ̀rọ ofin.
10 Nigbana ni o wi fun wọn pe, Ẹ lọ, ẹ jẹ ọ̀ra ki ẹ si mu ohun didùn, ki ẹ si fi apakan ipin ranṣẹ si awọn ti a kò pèse fun: nitori mimọ́ ni ọjọ yi fun Oluwa: ẹ máṣe banujẹ; nitori ayọ̀ Oluwa on li agbàra nyin.
11 Bẹ̃ni awọn ọmọ Lefi mu gbogbo enia dakẹ jẹ, wipe, ẹ dakẹ, nitori mimọ́ ni ọjọ yi; ẹ má si ṣe banujẹ.
12 Gbogbo awọn enia lọ lati jẹ ati lati mu ati lati fi ipin ranṣẹ, ati lati yọ ayọ̀ nla, nitoriti ọ̀rọ ti a sọ fun wọn ye wọn.
13 Li ọjọ keji awọn olori awọn baba gbogbo awọn enia, awọn alufa, ati awọn ọmọ Lefi pejọ si ọdọ Esra akọwe, ki o le fi ọ̀rọ ofin ye wọn.
14 Nwọn si ri a kọ sinu iwe-ofin, ti Oluwa ti pa li aṣẹ nipa ọwọ Mose pe, ki awọn ọmọ Israeli gbe inu agọ ni àse oṣu keje:
15 Pe, ki nwọn funrere, ki nwọn kede ni gbogbo ilu wọn, ati ni Jerusalemu, wipe, Ẹ jade lọ si òke, ki ẹ si mu ẹka igi olifi, ẹka igi pine, ati ẹka igi matili (myrtle) imọ ọpẹ, ati ẹka igi ti o tobi, lati ṣe agọ gẹgẹ bi a ti kọ ọ.
16 Bẹ̃ni awọn enia na jade lọ, nwọn si mu wọn wá, nwọn pa agọ fun ara wọn, olukuluku lori orule ile rẹ̀, ati li àgbala wọn, ati li àgbala ile Ọlọrun, ati ni ita ẹnu-bode omi, ati ni ita ẹnu-bode Efraimu.
17 Gbogbo ijọ enia ninu awọn ti o pada bọ̀ lati oko-ẹrú si pa agọ, nwọn si gbe abẹ awọn agọ na: nitori lati akokò Joṣua ọmọ Nuni wá, titi di ọjọ na awọn ọmọ Israeli kò ṣe bẹ̃. Ayọ̀ nlanla si wà.
18 Esra si kà ninu iwe ofin Ọlọrun li ojojumọ, lati ọjọ kini titi de ọjọ ikẹhin. Nwọn si pa àse na mọ li ọjọ meje, ati lọjọ kẹjọ, nwọn ni apejọ ti o ni ìronu gẹgẹ bi iṣe wọn.