1 AWỌN olori awọn enia si ngbe Jerusalemu: awọn enia iyokù si dìbo lati mu ẹnikan ninu ẹnimẹwa lati ma gbe Jerusalemu, ilu mimọ́, ati mẹsan iyokù lati ma gbe ilu miran.
2 Awọn enia si sure fun gbogbo awọn ọkunrin na ti nwọn yan ara wọn lati gbe Jerusalemu.
3 Wọnyi si ni awọn olori igberiko ti ngbe Jerusalemu, ṣugbọn ninu ilu Juda, olukuluku ngbe inu ilẹ ìni rẹ̀ ninu ilu wọn, eyini ni: awọn ọmọ Israeli, awọn alufa, ati awọn ọmọ Lefi, ati awọn Netinimu, ati awọn ọmọ awọn iranṣẹ Solomoni.
4 Ati ninu awọn ọmọ Juda ngbe Jerusalemu, ati ninu awọn ọmọ Benjamini. Ninu awọn ọmọ Juda, Ataiah ọmọ Ussiah, ọmọ Sekariah, ọmọ Amariah, ọmọ Ṣefatiah, ọmọ Mahalaleeli, ninu awọn ọmọ Peresi;
5 Ati Maaseiah ọmọ Baruku, ọmọ Kol-hose, ọmọ Hasaiah, ọmọ Adaiah, ọmọ Joiaribu, ọmọ Sekariah, ọmọ Ṣiloni.
6 Gbogbo ọmọ Peresi ti ngbe Jerusalemu jẹ adọrinlenirinwo o di meji, alagbara ọkunrin.
7 Wọnyi li awọn ọmọ Benjamini; Sallu ọmọ Meṣullamu ọmọ Joedi, ọmọ Pedaiah, ọmọ Kolaiah, ọmọ Maaseiah, ọmọ Itieli, ọmọ Jesaiah.
8 Ati lẹhin rẹ̀ Gabbai, Sallai, ọrindilẹgbẹrun o le mẹjọ.
9 Joeli ọmọ Sikri si ni alabojuto wọn; ati Juda ọmọ Senua ni igbakeji ni ilu.
10 Ninu awọn alufa: Jedaiah ọmọ Joiaribu, Jakini.
11 Seraiah ọmọ Hilkiah, ọmọ Meṣullamu, ọmọ Sadoku, ọmọ Meraioti, ọmọ Ahitibu, ni olori ile Ọlọrun.
12 Awọn arakunrin wọn ti o ṣe iṣẹ ile na jẹ, ẹgbẹrin o le mejilelogun: ati Adaiah ọmọ Jerohamu, ọmọ Pelaliah, ọmọ Amsi, ọmọ Sekariah, ọmọ Paṣuri, ọmọ Malkiah,
13 Ati awọn arakunrin rẹ̀, awọn olori awọn baba, ojilugba o le meji: ati Amaṣai ọmọ Asareeli, ọmọ Ahasai, ọmọ Meṣillemoti, ọmọ Immeri,
14 Ati awọn arakunrin wọn, alagbara li ogun, mejidilãdoje: ati olori wọn ni Sabdieli ọmọ ọkan ninu awọn enia nla.
15 Ninu awọn ọmọ Lefi pẹlu: Ṣemaiah, ọmọ Haṣubu, ọmọ Asrikamu, ọmọ Haṣabiah, ọmọ Bunni;
16 Ati Ṣabbetai ati Josabadi, ninu olori awọn ọmọ Lefi ni alabojuto iṣẹ ode ile Ọlọrun.
17 Ati Mattaniah ọmọ Mika, ọmọ Sabdi, ọmọ Asafu, ni olori lati bẹ̀rẹ idupẹ ninu adura: ati Bakbukiah ẹnikeji ninu awọn arakunrin rẹ̀, ati Abda ọmọ Ṣammua, ọmọ Galali, ọmọ Jedutuni.
18 Gbogbo awọn ọmọ Lefi ninu ilu mimọ́ jẹ ọrinlugba o le mẹrin.
19 Ati awọn adèna, Akkubu, Talmoni, ati awọn arakunrin wọn ti nṣọ ẹnu ọ̀na jẹ mejilelãdọsan.
20 Ati iyokù Israeli, ti awọn alufa, ati ti awọn ọmọ Lefi, wà ni gbogbo ilu Juda, olukuluku ninu ilẹ ìni rẹ̀.
21 Ṣugbọn awọn Netinimu ngbe Ofeli: ati Siha, ati Gispa wà li olori awọn Netinimu.
22 Ati alabojuto awọn ọmọ Lefi ni Jerusalemu ni Ussi ọmọ Bani, ọmọ Haṣabiah, ọmọ Mattaniah, ọmọ Mika. Ninu awọn ọmọ Asafu, awọn akọrin wà lori iṣẹ ile Ọlọrun.
23 Nitori o jẹ aṣẹ ọba nipa ti wọn, pe ki ipin kan ti o yẹ ki o jẹ ti awọn akọrin, li ojojumọ.
24 Ati Petahiah ọmọ Meṣesabeeli ninu awọn ọmọ Serah ọmọ Juda wà li ọwọ ọba ninu gbogbo awọn enia.
25 Ati fun ileto, pẹlu oko wọn, ninu awọn ọmọ Juda ngbe Kirjat-arba, ati ileto rẹ̀, ati ni Diboni, ati ileto rẹ̀, ati ni Jekabseeli, ati ileto rẹ̀,
26 Ati ni Jeṣua, ati ni Molada, ati ni Bet-feleti,
27 Ati ni Hasar-ṣuali, ati ni Beerṣeba, ati ileto rẹ̀,
28 Ati ni Siklagi, ati ni Mekona, ati ninu ileto rẹ̀,
29 Ati ni En-rimmoni, ati ni Sarea, ati Jarmuti,
30 Sanoa, Adullamu, ati ileto wọn, ni Lakiṣi, ati oko rẹ̀, ni Aseka, ati ileto rẹ̀. Nwọn si ngbe lati Beerṣeba titi de afonifoji Hinnomu.
31 Ati awọn ọmọ Benjamini lati Geba de Mikmaṣi, ati Aija, ati Beteli, ati ileto wọn.
32 Ni Anatotu, Nobu, Ananiah,
33 Hasori, Rama, Gittaimu,
34 Hadidi, Seboimu, Neballati,
35 Lodi, ati Ono, afonifoji awọn oniṣọnà,
36 Ati ninu awọn ọmọ Lefi, awọn ìpín Juda si ngbe ilẹ Benjamini.