Neh 9 YCE

Àwọn Eniyan náà Jẹ́wọ́ Ẹ̀ṣẹ̀ Wọn

1 LI ọjọ kẹrinlelogun oṣu yi, awọn ọmọ Israeli pejọ ninu àwẹ ati aṣọ ọ̀fọ, ati erupẹ lori wọn.

2 Awọn iru-ọmọ Israeli si ya ara wọn kuro ninu awọn ọmọ alejo, nwọn si duro, nwọn jẹwọ ẹ̀ṣẹ wọn, ati aiṣedede awọn baba wọn.

3 Nwọn si dide duro ni ipò wọn, nwọn si fi idamẹrin ọjọ kà ninu iwe ofin Oluwa Ọlọrun wọn; nwọn si fi idamẹrin jẹwọ, nwọn si sìn Oluwa Ọlọrun wọn.

4 Nigbana ni Jeṣua, ati Bani, Kadmieli, Ṣebaniah, Bunni, Ṣerebiah, Bani ati Kenani duro lori pẹtẹsì awọn ọmọ Lefi, nwọn si fi ohun rara kigbe si Oluwa Ọlọrun wọn.

5 Awọn ọmọ Lefi, Jeṣua, Kadmieli, Bani, Haṣabaiah, Ṣerebiah, Hodijah, Sebaniah, ati Pelaniah, si wipe: Ẹ dide, ki ẹ fi iyìn fun Oluwa Ọlọrun nyin lai ati lailai: ibukun si ni fun orukọ rẹ ti o li ogo, ti o ga jù gbogbo ibukun ati iyìn lọ.

6 Iwọ, ani iwọ nikanṣoṣo li Oluwa; iwọ li o ti dá ọrun, ọrun awọn ọrun pẹlu gbogbo ogun wọn, aiye, ati ohun gbogbo ti mbẹ ninu rẹ̀, okun, ati ohun gbogbo ti mbẹ̀ ninu rẹ̀, iwọ si pa gbogbo wọn mọ́ lãyè, ogun ọrun si nsìn ọ.

7 Iwọ ni Oluwa Ọlọrun, ti o ti yan Abramu, ti o si mu u jade lati Uri ti Kaldea wá, iwọ si sọ orukọ rẹ̀ ni Abrahamu;

8 Iwọ si ri pe ọkàn rẹ̀ jẹ olõtọ niwaju rẹ, iwọ si ba a dá majẹmu lati fi ilẹ awọn ara Kenaani, awọn ara Hitti, awọn ara Amori, ati awọn ara Perisi, ati awọn ara Jebusi, ati awọn ara Girgasi fun u, lati fi fun iru-ọmọ rẹ̀, iwọ si ti mu ọ̀rọ rẹ ṣẹ; nitori olododo ni iwọ:

9 Iwọ si ri ipọnju awọn baba wa ni Egipti, o si gbọ́ igbe wọn lẹba Okun Pupa;

10 O si fi ami, ati iṣẹ-iyanu hàn li ara Farao, ati li ara gbogbo iranṣẹ rẹ̀, ati li ara gbogbo enia ilẹ rẹ̀: nitori iwọ mọ̀ pe, nwọn hu ìwa igberaga si wọn. Iwọ si fi orukọ fun ara rẹ bi ti oni yi.

11 Iwọ si ti pin okun niwaju wọn, nwọn si la arin okun ja li ori ilẹ gbigbẹ; iwọ sọ awọn oninunibini wọn sinu ibú, bi okuta sinu omi lile.

12 Iwọ si fi ọwọ̀n awọ-sanma ṣe amọ̀na wọn li ọsan, ati li oru, ọwọ̀n iná, lati fun wọn ni imọlẹ li ọ̀na ninu eyiti nwọn o rin.

13 Iwọ si sọkalẹ wá si ori òke Sinai, o si bá wọn sọ̀rọ lati ọrun wá, o fun wọn ni idajọ titọ, ofin otitọ, ilana ati ofin rere.

14 Iwọ si mu ọjọ isimi mimọ rẹ di mimọ̀ fun wọn, o si paṣẹ ẹkọ́, ilana, ati ofin fun wọn, nipa ọwọ Mose iranṣẹ rẹ.

15 O si fun wọn li onjẹ lati ọrun wá fun ebi wọn, o si mu omi lati inu apata wá fun orungbẹ wọn, o si ṣe ileri fun wọn pe, ki nwọn lọ ijogun ilẹ na ti iwọ ti bura lati fi fun wọn.

16 Ṣugbọn awọn ati awọn baba wa hu ìwa igberaga, nwọn si mu ọrùn wọn le, nwọn kò si gba ofin rẹ gbọ́.

17 Nwọn si kọ̀ lati gbọràn, bẹ̃ni nwọn kò ranti iṣẹ iyanu ti iwọ ṣe li ãrin wọn; ṣugbọn nwọn mu ọrùn wọn le, ninu ìṣọtẹ wọn, nwọn yan olori lati pada si oko-ẹrú wọn: ṣugbọn iwọ li Ọlọrun ti o mura lati dariji, olore ọfẹ, ati alãnu, o lọra lati binu, o si ṣeun pipọ̀, o kò si kọ̀ wọn silẹ.

18 Nitõtọ nigbati nwọn ṣe ẹgbọrọ-malu didà, ti nwọn si wipe, Eyi li Ọlọrun rẹ ti o mu ọ gòke ti Egipti jade wá, nwọn si ṣe imunibinu nla.

19 Ṣugbọn iwọ, ninu ọ̀pọlọpọ ãnu rẹ, kò kọ̀ wọn silẹ li aginju, ọwọ̀n kũkũ kò kuro lọdọ wọn lojojumọ lati ṣe amọna wọn, bẹ̃ si li ọwọ̀n iná lati fun wọn ni imọlẹ li oru li ọ̀na ti nwọn iba rìn.

20 Iwọ fun wọn li ẹmi rere rẹ pẹlu lati kọ́ wọn, iwọ kò si gba manna rẹ kuro li ẹnu wọn, iwọ si fun wọn li omi fun orungbẹ wọn.

21 Nitotọ, ogoji ọdun ni iwọ fi bọ́ wọn li aginju, nwọn kò si ṣe alaini; aṣọ wọn kò gbó, ẹsẹ wọn kò si wú.

22 Pẹlupẹlu iwọ fi ijọba ati orilẹ-ède fun wọn, o si pin wọn si ìha gbogbo, bẹ̃ni nwọn jogun ilẹ Sihoni, ati ilẹ ọba Heṣboni, ati ilẹ Ogu, ọba Baṣani.

23 Awọn ọmọ wọn pẹlu ni iwọ sọ di pipọ bi irawọ ọrun, o si mu wọn wá ilẹ na sipa eyiti o ti leri fun awọn baba wọn pe: ki nwọn lọ sinu rẹ̀ lati gbà a.

24 Bẹ̃li awọn ọmọ na wọ inu rẹ̀ lọ, nwọn si gbà ilẹ na, iwọ si tẹ ori awọn ara ilẹ na ba niwaju wọn, awọn ara Kenaani, o si fi wọn le ọwọ wọn, pẹlu ọba wọn, ati awọn enia ilẹ na, ki nwọn ki o le fi wọn ṣe bi o ti wù wọn.

25 Nwọn si gbà ilu alagbara, ati ilẹ ọlọra, nwọn si gbà ilẹ ti o kún fun ohun rere, kanga, ọgba-ajara, ọgba-olifi, ati igi eleso, li ọ̀pọlọpọ: bẹ̃ni nwọ́n jẹ, nwọn si yo, nwọ́n sanra, nwọn si ni inu-didùn ninu ore rẹ nla.

26 Ṣugbọn nwọn ṣe alaigbọràn, nwọn si ṣọ̀tẹ si ọ, nwọn si gbe ofin rẹ sọ si ẹ̀hin wọn, nwọn si pa awọn woli rẹ ti nsọ fun wọn lati yipada si ọ, nwọn si ṣe imunibinu nla.

27 Nitorina ni iwọ fi wọn le ọwọ awọn ọta wọn, ti o pọn wọn loju, ati li akoko ipọnju wọn, nigbati nwọn kigbe pè ọ, iwọ gbọ́ lati ọrun wá; ati gẹgẹ bi ọ̀pọlọpọ ãnu rẹ, iwọ fun wọn li olugbala, ti nwọn gbà wọn kuro lọwọ awọn ọta wọn.

28 Ṣugbọn li ẹhin ti nwọn ni isimi, nwọn si tun ṣe buburu niwaju rẹ: nitorina ni iwọ fi wọn le ọwọ awọn ọta wọn, tobẹ̃ ti nwọn jọba li ori wọn: ṣugbọn nigbati nwọn pada, ti nwọn si kigbe pè ọ, iwọ gbọ́ lati ọrun wá, ọ̀pọlọpọ ìgba ni iwọ si gbà wọn gẹgẹ bi ãnu rẹ.

29 Iwọ si jẹri gbè wọn ki iwọ ki o le tun mu wọn wá sinu ofin rẹ, ṣugbọn nwọn hu ìwa igberaga, nwọn kò si fi eti si ofin rẹ, nwọn si ṣẹ̀ si idajọ rẹ (eyiti bi enia ba ṣe on o yè ninu wọn), nwọn si gún èjika, nwọn mu ọrùn wọn le, nwọn kò si fẹ igbọ́.

30 Sibẹ ọ̀pọlọpọ ọdun ni iwọ fi mu suru fun wọn ti o si fi ẹmi rẹ jẹri gbè wọn ninu awọn woli rẹ: sibẹ̀ nwọn kò fi eti silẹ: nitorina ni iwọ ṣe fi wọn le ọwọ awọn enia ilẹ wọnni.

31 Ṣugbọn nitori ãnu rẹ nla iwọ kò run wọn patapata, bẹ̃ni iwọ kò kọ̀ wọn silẹ; nitori iwọ li Ọlọrun olore-ọfẹ ati alãnu.

32 Njẹ nitorina, Ọlọrun wa, Ọlọrun ti o tobi, ti o li agbara, ti o si li ẹ̀ru, ẹniti npa majẹmu ati ãnu mọ, má jẹ ki gbogbo iyọnu na dabi ohun kekere niwaju rẹ, o de bá wa, awọn ọba wa, awọn ijoye wa, ati awọn alufa wa, ati awọn woli wa, ati awọn baba wa, ati gbogbo awọn enia rẹ lati akoko ọba Assiria wá, titi o fi di oni yi.

33 Sibẹ, iwọ ṣe olododo ninu ohun gbogbo ti o de ba wa, iwọ si ti ṣe otitọ, ṣugbọn awa ti ṣe buburu:

34 Awọn ọba wa, awọn ijoye wa, awọn alufa wa, ati awọn baba wa, kò pa ofin rẹ mọ, bẹ̃ni nwọn kò fi eti si aṣẹ rẹ, ati ẹri rẹ, ti iwọ fi jẹri gbè wọn.

35 Nitori ti nwọn kò sin ọ ninu ijọba wọn, ati ninu ore rẹ nla ti iwọ fi fun wọn, ati ninu ilẹ nla ati ọlọra ti o fi si iwaju wọn, bẹ̃ni nwọn kò pada kuro ninu iṣẹ buburu wọn.

36 Kiyesi i, ẹrú li awa iṣe li oni yi, ati ilẹ ti iwọ fi fun awọn baba wa lati ma jẹ eso rẹ̀, ati ire rẹ̀, kiyesi i, awa jẹ ẹrú ninu rẹ̀.

37 Ilẹ na si mu ohun ọ̀pọlọpọ wá fun awọn ọba, ti iwọ ti fi ṣe olori wa nitori ẹ̀ṣẹ wa: nwọn ni aṣẹ lori ara wa pẹlu, ati lori ẹran-nla wa, bi o ti wù wọn, awa si wà ninu wàhala nla.

38 Ati nitori gbogbo eyi awa dá majẹmu ti o daju, a si kọwe rẹ̀; awọn ìjoye wa, awọn ọmọ Lefi, ati awọn alufa si fi èdidi di i.

orí

1 2 3 4 5 6 7 8 9 10 11 12 13